Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkún Jeremaya 2:5-8 BIBELI MIMỌ (BM)

5. OLUWA ṣe bí ọ̀tá,ó ti pa Israẹli run.Ó ti pa gbogbo ààfin rẹ̀ run,ó sọ àwọn ibi ààbò rẹ̀ di àlàpàó sì sọ ọ̀fọ̀ ati ẹkún Juda di pupọ.

6. Ó wó àgọ́ rẹ̀ lulẹ̀,bí ìgbà tí eniyan wó ahéré oko.Ó pa gbogbo ibi tí wọ́n ti ń ṣe àwọn àjọ̀dún tí a yà sọ́tọ̀ run.OLUWA ti fi òpin sí àwọn àjọ̀dún tí a yà sọ́tọ̀, ati ọjọ́ ìsinmi ní Sioni.Ó sì ti fi ibinu gbígbóná rẹ̀,kọ ọba ati alufaa sílẹ̀.

7. OLUWA kò bìkítà fún pẹpẹ rẹ̀ mọ́,ó sì ti kọ ibi mímọ́ rẹ̀ sílẹ̀.Ó ti fi odi ààfin rẹ̀ lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́;wọ́n pariwo ńlá ninu ilé OLUWAgẹ́gẹ́ bíi ti ọjọ́ àjọ̀dún tí a yà sọ́tọ̀.

8. OLUWA ti pinnu láti wó odi Sioni lulẹ̀.Ó fi okùn ìwọ̀n wọ̀n ọ́n,kò sì rowọ́ láti parun.Ó jẹ́ kí ilé ìṣọ́ ati odi ìlú wó lulẹ̀ pẹlu ìbànújẹ́,wọ́n sì di àlàpà papọ̀.

Ka pipe ipin Ẹkún Jeremaya 2