Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkún Jeremaya 2:13-18 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Kí ni mo lè sọ nípa rẹ,kí sì ni ǹ bá fi ọ́ wé, Jerusalẹmu?Kí ni mo lè fi wé ọ,kí n lè tù ọ́ ninu, ìwọ Sioni?Nítorí bí omi òkun ni ìparun rẹ gbòòrò;ta ló lè mú ọ pada bọ̀ sípò?

14. Ìran èké ati ti ẹ̀tàn ni àwọn wolii rẹ ń rí sí ọ;wọn kò fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ hàn ọ́,kí wọ́n lè dá ire rẹ pada,ṣugbọn wọ́n ń ríran èké ati ìran ẹ̀tàn sí ọ.

15. Gbogbo àwọn tí ń rékọjá lọń pàtẹ́wọ́ lé ọ lórí,wọ́n ń pòṣé,wọ́n sì ń mi orí wọn sí ọ, Jerusalẹmu.Wọ́n ń sọ pé:“Ṣé ìlú yìí ni à ń pè níìlú tí ó lẹ́wà jùlọ,tí ó jẹ́ ayọ̀ gbogbo ayé?”

16. Gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ ń fi ọ́ ṣẹ̀sín,wọ́n ń pòṣé,wọ́n ń fi ọ́ ṣe ẹlẹ́yà.Wọ́n ń wí pé:“A ti pa á run!Ọjọ́ tí a tí ń retí nìyí;ọwọ́ wa ti tẹ Jerusalẹmu wàyí!A ti rí ohun tí à ń wá!”

17. OLUWA ti ṣe bí ó ti pinnu,ó ti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ,bí ó ti sọ ní ìgbà àtijọ́.Ó ti wó ọ lulẹ̀ láìṣàánú rẹ;ó ti jẹ́ kí ọ̀tá yọ̀ ọ́,ó ti fún àwọn ọ̀tá rẹ ni agbára kún agbára.

18. Ẹ kígbe sí OLUWA,ẹ̀yin ará Sioni!Ẹ jẹ́ kí omi máa dà lójú yín pòròpòrò tọ̀sán-tòru;ẹ má sinmi,ẹ má sì jẹ́ kí oorun kùn yín.

Ka pipe ipin Ẹkún Jeremaya 2