Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkún Jeremaya 1:12-17 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Ó ní, “Ṣé ọ̀rọ̀ yìí kò kàn yín ni,gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń kọjá lọ?Ẹ̀yin náà ẹ wò ó, kí ẹ ṣe akiyesi rẹ̀,bóyá ìbànújẹ́ kan wàtí ó dàbí èyí tí ó dé bá mi yìí;tí OLUWA mú kí ó dé bá mi,ní ọjọ́ ibinu gbígbóná rẹ̀.

13. “Ó rán iná láti òkè ọ̀run wá;ó dá a sí egungun mi;ó dẹ àwọ̀n sílẹ̀ fún mi;ó sì dá mi pada.Mo dàbí odi,mo sì fi ìgbà gbogbo dákú.

14. “Ó di ẹ̀ṣẹ̀ mi bí àjàgà,ó gbé e kọ́ mi lọ́rùn,ó sì sọ mí di aláìlágbára.OLUWA ti fi mí léàwọn tí n kò lè dojú kọ lọ́wọ́.

15. “OLUWA ti fi ẹsẹ̀ tẹ àwọn akọni mi mọ́lẹ̀;ó pe ọpọlọpọ eniyan jọ sí mi,ó ní kí wọ́n pa àwọn ọdọmọkunrin mi;OLUWA ti tẹ àwọn ọmọ Juda ní àtẹ̀rẹ́,bí ẹni tẹ èso àjàrà fún ọtí waini.

16. “Nítorí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọnyi ni mo ṣe sọkún;tí omijé ń dà lójú mi;olùtùnú jìnnà sí mi,kò sí ẹni tí ó lè dá mi lọ́kàn le.Àwọn ọmọ mi ti di aláìní,nítorí pé àwọn ọ̀tá ti borí wa.

17. “Sioni na ọwọ́ rẹ̀ fún ìrànwọ́,Ṣugbọn kò sí ẹni tí ó ràn án lọ́wọ́,OLUWA ti pàṣẹ pé,kí àwọn aládùúgbò Jakọbu di ọ̀tá rẹ̀;Jerusalẹmu sì ti di eléèérí láàrin wọn.

Ka pipe ipin Ẹkún Jeremaya 1