Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 8:1-6 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Lẹ́yìn náà OLUWA sọ fún Mose pé, “Lọ sí ọ̀dọ̀ Farao, kí o sì wí fún un pé, ‘OLUWA ní, “Jẹ́ kí àwọn eniyan mi lọ sìn mí.

2. Ṣugbọn bí o bá kọ̀, tí o kò jẹ́ kí wọ́n lọ, n óo da ọ̀pọ̀lọ́ bo ilẹ̀ rẹ.

3. Àwọn ọ̀pọ̀lọ́ yóo máa gbá yìnìn ninu odò Naili, wọn yóo sì wọ inú ààfin rẹ ati yàrá tí ò ń sùn, wọn yóo gun orí ibùsùn rẹ, wọn yóo sì wọ ilé àwọn ẹmẹ̀wà rẹ, ati ti àwọn eniyan rẹ. N óo dà wọ́n sinu ilé ìdáná ati sinu àwo tí wọ́n fi ń tọ́jú oúnjẹ.

4. Àwọn ọ̀pọ̀lọ́ náà yóo máa fò mọ́ ìwọ, ati àwọn eniyan rẹ ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ.” ’ ”

5. OLUWA rán Mose pé, “Sọ fún Aaroni pé kí ó na ọwọ́ rẹ̀ ati ọ̀pá rẹ̀ sórí àwọn odò ati àwọn adágún tí wọ́n gbẹ́, ati sórí gbogbo ibi tí omi dárogún sí, kí àwọn ọ̀pọ̀lọ́ lè jáde sórí ilẹ̀ Ijipti.”

6. Aaroni bá na ọwọ́ rẹ̀ sí orí gbogbo omi ilẹ̀ Ijipti, ọ̀pọ̀lọ́ bá wọ́ jáde, wọ́n sì bo gbogbo ilẹ̀ Ijipti.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 8