Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 7:1-6 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA bá dá Mose lóhùn pé, “Wò ó, mo ti sọ ọ́ di ọlọrun fún Farao, Aaroni, arakunrin rẹ ni yóo sì jẹ́ wolii rẹ.

2. Gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún ọ ni kí o sọ; Aaroni, arakunrin rẹ yóo sì sọ fún Farao pé kí ó jẹ́ kí àwọn eniyan Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀.

3. Ṣugbọn n óo mú kí ọkàn Farao le, tóbẹ́ẹ̀ tí yóo fi jẹ́ pé, bí ó ti wù kí iṣẹ́ ìyanu tí n óo ṣe ní ilẹ̀ Ijipti pọ̀ tó, kò ní gbọ́ tìrẹ.

4. Nígbà náà ni n óo nawọ́ ìyà sí Ijipti, n óo sì kó àwọn ọmọ Israẹli, ìjọ eniyan mi, jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti pẹlu iṣẹ́ ìyanu ati ìdájọ́ ńlá.

5. Àwọn ará Ijipti yóo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA, nígbà tí mo bá nawọ́ ìyà sí Ijipti tí mo sì kó àwọn eniyan Israẹli jáde kúrò láàrin wọn.”

6. Mose ati Aaroni bá ṣe bí OLUWA ti pa á láṣẹ fún wọn.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 7