Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 40:18-35 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Mose pa àgọ́ mímọ́ náà, ó to àwọn ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀, ó gbé àwọn àkànpọ̀ igi rẹ̀ lé wọn, ó fi àwọn igi ìdábùú àgọ́ náà dábùú àwọn àkànpọ̀ igi rẹ̀; lẹ́yìn náà, ó gbé àwọn òpó rẹ̀ nàró.

19. Lẹ́yìn náà, ó ta aṣọ àgọ́ náà bò ó, ó sì fi ìbòrí rẹ̀ bò ó gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.

20. Ó kó àwọn tabili òkúta mejeeji sinu àpótí ẹ̀rí náà, ó ti àwọn ọ̀pá àpótí náà bọ inú àwọn òrùka rẹ̀, ó sì fi ìdérí rẹ̀ dé e lórí.

21. Ó gbé àpótí ẹ̀rí náà sinu àgọ́ náà, ó sì ta aṣọ ìbòjú rẹ̀ dí i gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.

22. Ó gbé tabili náà sí inú àgọ́, ní apá ìhà àríwá àgọ́ mímọ́, níwájú aṣọ ìbòjú,

23. ó sì to àwọn burẹdi náà létòlétò sórí rẹ̀ níwájú OLUWA, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.

24. Ó gbé ọ̀pá fìtílà náà sinu àgọ́ àjọ níwájú tabili ní apá ìhà gúsù àgọ́ náà.

25. Ó to àwọn fìtílà rẹ̀ sórí rẹ̀ níwájú OLUWA gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.

26. Ó gbé pẹpẹ wúrà náà kalẹ̀ ninu àgọ́ àjọ níwájú aṣọ ìbòjú náà,

27. ó sì sun turari olóòórùn dídùn lórí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.

28. Ó ta àwọn aṣọ títa ti ẹnu ọ̀nà àgọ́ náà sí ààyè wọn.

29. Ó gbé pẹpẹ ẹbọ sísun kalẹ̀ níbi ẹnu ọ̀nà àgọ́ náà, ó sì rú ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.

30. Ó gbé agbada omi náà kalẹ̀ ní agbede meji àgọ́ àjọ ati pẹpẹ ẹbọ sísun, ó sì pọn omi sinu rẹ̀.

31. Omi yìí ni Mose, ati Aaroni ati àwọn ọmọ Aaroni fi ń fọ ọwọ́ ati ẹsẹ̀ wọn,

32. nígbà tí wọ́n bá ń wọ inú àgọ́ àjọ lọ, ati ìgbà tí wọ́n bá fẹ́ súnmọ́ ìdí pẹpẹ, wọn á fọ ọwọ́ ati ẹsẹ̀ wọn gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ.

33. Ó ṣe àgbàlá kan yí àgọ́ ati pẹpẹ náà ká, ó ta aṣọ sí ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà. Bẹ́ẹ̀ ni Mose ṣe parí gbogbo iṣẹ́ náà.

34. Nígbà náà ni ìkùukùu bo àgọ́ àjọ náà, ògo OLUWA sì kún inú rẹ̀.

35. Mose kò sì lè wọ inú rẹ̀ nítorí ìkùukùu tí ó wà lórí rẹ̀, ati pé ògo OLUWA kún inú rẹ̀.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 40