Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 40:18-32 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Mose pa àgọ́ mímọ́ náà, ó to àwọn ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀, ó gbé àwọn àkànpọ̀ igi rẹ̀ lé wọn, ó fi àwọn igi ìdábùú àgọ́ náà dábùú àwọn àkànpọ̀ igi rẹ̀; lẹ́yìn náà, ó gbé àwọn òpó rẹ̀ nàró.

19. Lẹ́yìn náà, ó ta aṣọ àgọ́ náà bò ó, ó sì fi ìbòrí rẹ̀ bò ó gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.

20. Ó kó àwọn tabili òkúta mejeeji sinu àpótí ẹ̀rí náà, ó ti àwọn ọ̀pá àpótí náà bọ inú àwọn òrùka rẹ̀, ó sì fi ìdérí rẹ̀ dé e lórí.

21. Ó gbé àpótí ẹ̀rí náà sinu àgọ́ náà, ó sì ta aṣọ ìbòjú rẹ̀ dí i gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.

22. Ó gbé tabili náà sí inú àgọ́, ní apá ìhà àríwá àgọ́ mímọ́, níwájú aṣọ ìbòjú,

23. ó sì to àwọn burẹdi náà létòlétò sórí rẹ̀ níwájú OLUWA, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.

24. Ó gbé ọ̀pá fìtílà náà sinu àgọ́ àjọ níwájú tabili ní apá ìhà gúsù àgọ́ náà.

25. Ó to àwọn fìtílà rẹ̀ sórí rẹ̀ níwájú OLUWA gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.

26. Ó gbé pẹpẹ wúrà náà kalẹ̀ ninu àgọ́ àjọ níwájú aṣọ ìbòjú náà,

27. ó sì sun turari olóòórùn dídùn lórí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.

28. Ó ta àwọn aṣọ títa ti ẹnu ọ̀nà àgọ́ náà sí ààyè wọn.

29. Ó gbé pẹpẹ ẹbọ sísun kalẹ̀ níbi ẹnu ọ̀nà àgọ́ náà, ó sì rú ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.

30. Ó gbé agbada omi náà kalẹ̀ ní agbede meji àgọ́ àjọ ati pẹpẹ ẹbọ sísun, ó sì pọn omi sinu rẹ̀.

31. Omi yìí ni Mose, ati Aaroni ati àwọn ọmọ Aaroni fi ń fọ ọwọ́ ati ẹsẹ̀ wọn,

32. nígbà tí wọ́n bá ń wọ inú àgọ́ àjọ lọ, ati ìgbà tí wọ́n bá fẹ́ súnmọ́ ìdí pẹpẹ, wọn á fọ ọwọ́ ati ẹsẹ̀ wọn gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 40