Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 40:1-16 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA sọ fún Mose pé,

2. “Kọ́ àgọ́ ìpàdé ní ọjọ́ kinni oṣù kinni.

3. Kí o sì gbé àpótí ẹ̀rí tí òfin mẹ́wàá wà ninu rẹ̀ sinu àgọ́ náà, kí o sì ta aṣọ ìbòjú dí i.

4. Lẹ́yìn náà, gbé tabili náà wọ inú rẹ̀, pẹlu àwọn nǹkan tí wọn yóo máa lò pẹlu rẹ̀, kí o sì tò wọ́n sí ààyè wọn. Lẹ́yìn náà, gbé ọ̀pá fìtílà náà wọ inú rẹ̀, kí o sì to àwọn fìtílà orí rẹ̀ sí ààyè wọn.

5. Lẹ́yìn náà, gbé pẹpẹ wúrà turari siwaju àpótí ẹ̀rí náà, kí o sì ta aṣọ sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ náà.

6. Gbé pẹpẹ ẹbọ sísun kalẹ̀ níwájú ẹnu ọ̀nà àgọ́ mímọ́ ti àgọ́ àjọ náà.

7. Gbé agbada omi náà sí ààrin, ní agbede meji àgọ́ àjọ ati pẹpẹ náà, kí o sì pọn omi sinu rẹ̀.

8. Lẹ́yìn náà, ṣe àgbàlá yí i ká, kí o sì ta aṣọ sí ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà.

9. “Lẹ́yìn náà, mú òróró ìyàsímímọ́, kí o ta á sí ara àgọ́ náà, ati sí ara ohun gbogbo tí ó wà ninu rẹ̀, kí o yà á sí mímọ́ pẹlu gbogbo àwọn ohun èlò inú rẹ̀, wọn yóo sì di mímọ́.

10. Ta òróró sí ara pẹpẹ ẹbọ sísun pẹlu, ati sí ara gbogbo àwọn ohun èlò rẹ̀, kí o ya pẹpẹ náà sí mímọ́, pẹpẹ náà yóo sì di ohun mímọ́ jùlọ.

11. Ta òróró sí ara agbada náà pẹlu ati gbogbo ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀, kí o sì yà á sí mímọ́.

12. “Lẹ́yìn náà, mú Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ àjọ, kí o sì fi omi wẹ̀ wọ́n.

13. Kó àwọn ẹ̀wù mímọ́ náà wọ Aaroni, ta òróró sí i lórí, kí o sì yà á sí mímọ́ kí ó lè máa ṣe alufaa mi.

14. Kó àwọn ọmọ rẹ̀ wá pẹlu, kí o sì wọ̀ wọ́n ní ẹ̀wù.

15. Ta òróró sí wọn lórí, gẹ́gẹ́ bí o ti ta á sí baba wọn lórí, kí àwọn náà lè máa ṣe alufaa mi. Òróró tí o bá ta sí wọn lórí ni yóo sọ àwọn ati gbogbo ìran wọn di alufaa títí lae.”

16. Mose ṣe gbogbo ohun tí OLUWA pa láṣẹ fún un patapata.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 40