Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 4:8-16 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Ọlọrun ní, “Bí wọn kò bá fẹ́ gbà ọ́ gbọ́, tabi bí wọn kò bá náání àmì ti àkọ́kọ́, ó ṣeéṣe kí wọ́n gba àmì keji yìí gbọ́.

9. Bí wọn kò bá gba àwọn àmì mejeeji wọnyi gbọ́, tí wọ́n sì kọ̀, tí wọn kò gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ, lọ bu omi díẹ̀ ninu odò Naili kí o sì dà á sí orí ìyàngbẹ ilẹ̀; omi náà yóo di ẹ̀jẹ̀ bí o bá ti dà á sí orí ìyàngbẹ ilẹ̀.”

10. Ṣugbọn Mose wí fún OLUWA pé, “OLUWA mi, n kò lè sọ̀rọ̀ dáradára kí o tó bá mi sọ̀rọ̀, bẹ́ẹ̀ náà sì ni lẹ́yìn tí o bá èmi iranṣẹ rẹ sọ̀rọ̀ tán, nítorí pé akólòlò ni mí.”

11. OLUWA dá a lóhùn pé, “Ta ló dá ẹnu eniyan? Ta ni í mú kí eniyan ya odi, tabi kí ó ya adití, tabi kí ó ríran, tabi kí ó ya afọ́jú? Ṣebí èmi OLUWA ni.

12. Nítorí náà, lọ, n óo sì wà pẹlu rẹ, n óo sì máa kọ́ ọ ní ohun tí o óo sọ.”

13. Ṣugbọn Mose tún ní, “OLUWA mi, mo bẹ̀ ọ́, rán ẹlòmíràn.”

14. Inú bí OLUWA sí Mose, ó ní, “Ṣebí Aaroni, ọmọ Lefi, arakunrin rẹ wà níbẹ̀? Mo mọ̀ pé òun lè sọ̀rọ̀ dáradára; ó ń bọ̀ wá pàdé rẹ, nígbà tí ó bá rí ọ, inú rẹ̀ yóo dùn gidigidi.

15. O óo máa bá a sọ̀rọ̀, o óo sì fi ọ̀rọ̀ sí i lẹ́nu. N óo gbàkóso ẹnu rẹ ati ẹnu rẹ̀; n óo sì kọ yín ní ohun tí ẹ óo ṣe.

16. Òun ni yóo máa bá ọ bá àwọn eniyan sọ̀rọ̀, yóo jẹ́ ẹnu fún ọ, o óo sì dàbí Ọlọrun fún un.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 4