Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 4:4-8 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Ṣugbọn OLUWA sọ fún Mose pé, “Na ọwọ́ rẹ, kí o mú un ní ìrù.” Mose nawọ́ mú un, ejò náà sì pada di ọ̀pá ní ọwọ́ rẹ̀.

5. OLUWA wí pé, “Èyí yóo mú kí wọ́n gbàgbọ́ pé OLUWA, Ọlọrun àwọn baba wọn, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki ati Ọlọrun Jakọbu ni ó farahàn ọ́.”

6. OLUWA tún wí fún un pé, “Ti ọwọ́ rẹ bọ abíyá.” Mose sì ti ọwọ́ bọ abíyá. Nígbà tí ó yọ ọ́ jáde, ọwọ́ rẹ̀ dẹ́tẹ̀, ó sì funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú.

7. Ọlọrun tún ní, “Ti ọwọ́ rẹ bọ abíyá pada.” Mose sì ti ọwọ́ bọ abíyá rẹ̀ pada; nígbà tí ó yọ ọ́ jáde, ọwọ́ rẹ̀ pada sí bí ó ti wà tẹ́lẹ̀.

8. Ọlọrun ní, “Bí wọn kò bá fẹ́ gbà ọ́ gbọ́, tabi bí wọn kò bá náání àmì ti àkọ́kọ́, ó ṣeéṣe kí wọ́n gba àmì keji yìí gbọ́.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 4