Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 39:8-17 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Irú aṣọ tí wọ́n fi ṣe efodu náà ni wọ́n fi ṣe ìgbàyà rẹ̀, wọ́n fi wúrà, aṣọ aláwọ̀ aró, ti elése àlùkò, aṣọ pupa ati aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ ṣe iṣẹ́ ọnà sí i lára.

9. Bákan náà ni òòró ati ìbú aṣọ ìgbàyà náà, ìṣẹ́po aṣọ meji ni wọ́n sì rán pọ̀. Ìká kan ni òòró rẹ̀, ìká kan náà sì ni ìbú rẹ̀.

10. Wọ́n to òkúta olówó iyebíye sí i lára ní ẹsẹ̀ mẹrin, wọ́n to òkúta sadiu ati topasi ati kabọnku sí ẹsẹ̀ kinni,

11. wọ́n to emeradi ati safire ati dayamọndi sí ẹsẹ̀ keji,

12. wọ́n to jasiniti, agate ati ametisti sí ẹsẹ̀ kẹta;

13. wọ́n to bẹrili ati onikisi ati Jasperi sí ẹsẹ̀ kẹrin, wọ́n sì fi ìtẹ́lẹ̀ wúrà jó wọn mọ́ ìgbàyà náà.

14. Oríṣìí òkúta mejila ni ó wà níbẹ̀; orúkọ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn dúró fún orúkọ ẹ̀yà àwọn ọmọ Israẹli kọ̀ọ̀kan, wọ́n dàbí èdìdì, wọn sì kọ orúkọ àwọn ẹ̀yà Israẹli mejeejila sí wọn lára, òkúta kan fún ẹ̀yà kan.

15. Wọ́n fi ojúlówó wúrà ṣe ẹ̀wọ̀n tí a lọ́pọ̀ gẹ́gẹ́ bí okùn fún ìgbàyà náà.

16. Wọ́n ṣe ojú ìdè wúrà meji, ati òrùka wúrà meji, wọ́n fi òrùka wúrà mejeeji sí etí kinni keji ìgbàyà náà.

17. Wọ́n ti àwọn ẹ̀wọ̀n wúrà mejeeji náà bọ àwọn òrùka mejeeji tí wọ́n wà ní etí kinni keji ìgbàyà náà.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 39