Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 39:28-41 BIBELI MIMỌ (BM)

28. wọ́n fi ṣe adé, ati fìlà ati ṣòkòtò.

29. Wọ́n fi aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́, ti aláwọ̀ aró, ti elése àlùkò ati aṣọ pupa tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí lára ṣe àmùrè gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.

30. Wọ́n fi ojúlówó wúrà ṣe ìgbátí adé mímọ́ náà, wọ́n sì kọ àkọlé kan sí ara rẹ̀ bí wọ́n ti ń kọ ọ́ sí ara òrùka èdìdì, pé, “Mímọ́ fún OLUWA.”

31. Wọ́n so aṣọ aláwọ̀ aró tẹ́ẹ́rẹ́ kan mọ́ ọn, láti máa fi so ó mọ́ etí adé náà gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.

32. Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo iṣẹ́ àgọ́ àjọ náà ṣe parí, àwọn ọmọ Israẹli ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.

33. Wọ́n sì gbé àgọ́ àjọ náà tọ Mose wá, àgọ́ náà ati gbogbo àwọn ohun èlò inú rẹ̀, àwọn ìkọ́ rẹ̀, àwọn àkànpọ̀ igi inú rẹ̀, àwọn igi ìdábùú inú rẹ̀, àwọn òpó rẹ̀, ati àwọn ìtẹ́lẹ̀ wọn;

34. ìbòrí tí wọ́n fi awọ ewúrẹ́ ati awọ àgbò ṣe tí wọ́n kùn láwọ̀ pupa, ati aṣọ ìbòjú inú àgọ́ náà.

35. Bẹ́ẹ̀ náà ni àpótí ẹ̀rí pẹlu àwọn òpó rẹ̀ ati ìtẹ́ àánú náà;

36. ati tabili náà, pẹlu gbogbo àwọn ohun èlò rẹ̀ ati burẹdi ìfihàn.

37. Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀pá fìtílà tí a fi ojúlówó wúrà ṣe, ati àwọn fìtílà orí rẹ̀, pẹlu gbogbo àwọn ohun èlò rẹ̀, ati òróró ìtànná rẹ̀.

38. Bẹ́ẹ̀ sì ni pẹpẹ wúrà náà, ati òróró ìyàsímímọ́, ati turari olóòórùn dídùn, ati aṣọ títa fún ìlẹ̀kùn àgọ́ mímọ́ náà;

39. ati pẹpẹ idẹ ati ààrò idẹ rẹ̀, àwọn ọ̀pá rẹ̀ ati gbogbo ohun èlò rẹ̀, agbada idẹ ati ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀.

40. Bẹ́ẹ̀ náà ni aṣọ títa ti àgbàlá náà, àwọn òpó rẹ̀ ati àwọn ìtẹ́lẹ̀ wọn, ati aṣọ fún ẹnu ọ̀nà àgọ́ náà, okùn rẹ̀ ati àwọn èèkàn rẹ̀, ati gbogbo ohun èlò fún ìsìn ninu àgọ́ mímọ́ náà, ati fún àgọ́ àjọ náà.

41. Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ẹ̀wù tí a ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ọnà sí fún iṣẹ́ ìsìn àwọn alufaa ninu ibi mímọ́, ẹ̀wù mímọ́ fún Aaroni alufaa ati ẹ̀wù fún àwọn ọmọ rẹ̀ náà, tí wọn yóo fi máa ṣe iṣẹ́ wọn bí alufaa.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 39