Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 39:2-14 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Ó fi wúrà, aṣọ aláwọ̀ aró, ti elése àlùkò ati aṣọ pupa ati aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ rán efodu.

3. Ó fi òòlù lu wúrà, ó sì gé e tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ bí okùn, wọ́n fi ṣe iṣẹ́ ọnà sára aṣọ aláwọ̀ aró ati ti elése àlùkò ati aṣọ pupa ati aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́.

4. Wọ́n ṣe aṣọ tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ meji fún èjìká efodu náà, wọ́n rán wọn mọ́ ẹ̀gbẹ́ kinni keji rẹ̀ láti máa fi so wọ́n mọ́ ara wọn.

5. Wọ́n fi irú aṣọ kan náà ṣe àmùrè dáradára kan. Àṣepọ̀ ni wọ́n ṣe é mọ́ efodu yìí láti máa fi so ó gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.

6. Wọ́n tọ́jú àwọn òkúta onikisi, wọ́n jó wọn mọ́ ojú ìtẹ́lẹ̀ wúrà, wọ́n kọ orúkọ àwọn ẹ̀yà Israẹli sí ara wọn, bí wọ́n ti máa ń kọ orúkọ sí ara òrùka èdìdì.

7. Ó tò wọ́n sí ara èjìká efodu náà gẹ́gẹ́ bí òkúta ìrántí fún àwọn ọmọ Israẹli, bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.

8. Irú aṣọ tí wọ́n fi ṣe efodu náà ni wọ́n fi ṣe ìgbàyà rẹ̀, wọ́n fi wúrà, aṣọ aláwọ̀ aró, ti elése àlùkò, aṣọ pupa ati aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ ṣe iṣẹ́ ọnà sí i lára.

9. Bákan náà ni òòró ati ìbú aṣọ ìgbàyà náà, ìṣẹ́po aṣọ meji ni wọ́n sì rán pọ̀. Ìká kan ni òòró rẹ̀, ìká kan náà sì ni ìbú rẹ̀.

10. Wọ́n to òkúta olówó iyebíye sí i lára ní ẹsẹ̀ mẹrin, wọ́n to òkúta sadiu ati topasi ati kabọnku sí ẹsẹ̀ kinni,

11. wọ́n to emeradi ati safire ati dayamọndi sí ẹsẹ̀ keji,

12. wọ́n to jasiniti, agate ati ametisti sí ẹsẹ̀ kẹta;

13. wọ́n to bẹrili ati onikisi ati Jasperi sí ẹsẹ̀ kẹrin, wọ́n sì fi ìtẹ́lẹ̀ wúrà jó wọn mọ́ ìgbàyà náà.

14. Oríṣìí òkúta mejila ni ó wà níbẹ̀; orúkọ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn dúró fún orúkọ ẹ̀yà àwọn ọmọ Israẹli kọ̀ọ̀kan, wọ́n dàbí èdìdì, wọn sì kọ orúkọ àwọn ẹ̀yà Israẹli mejeejila sí wọn lára, òkúta kan fún ẹ̀yà kan.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 39