Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 39:19-33 BIBELI MIMỌ (BM)

19. Lẹ́yìn náà wọ́n da òrùka wúrà meji, wọ́n sì dè wọ́n mọ́ etí kinni keji ìgbàyà náà, lọ́wọ́ inú ní ẹ̀gbẹ́ tí ó kan ara efodu.

20. Wọ́n sì da òrùka wúrà meji mìíràn, wọ́n dè wọ́n mọ́ ìsàlẹ̀ èjìká efodu náà níwájú, lókè ibi tí ó ti so pọ̀ mọ́ àmùrè rẹ̀.

21. Òrùka aṣọ ìgbàyà yìí ni wọ́n fi dè é mọ́ òrùka ara efodu pẹlu aṣọ aláwọ̀ aró tẹ́ẹ́rẹ́ kan, kí ó lè sùn lé àmùrè efodu náà tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí lára, kí ìgbàyà náà má baà tú kúrò lára efodu, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.

22. Ó fi aṣọ aláwọ̀ aró rán ẹ̀wù àwọ̀kanlẹ̀ sí efodu náà,

23. wọ́n yọ ọrùn sí ẹ̀wù àwọ̀kanlẹ̀ náà bí ọrùn ẹ̀wù gan-an, wọ́n sì fi aṣọ tẹ́ẹ́rẹ́ gbá a yípo kí ó má baà ya.

24. Wọ́n fi aṣọ aláwọ̀ aró, ti elése àlùkò, ati aṣọ pupa ati aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ ṣe àwòrán èso Pomegiranate sí etí ẹ̀wù àwọ̀kanlẹ̀ náà nísàlẹ̀.

25. Wọ́n sì fi agogo ojúlówó wúrà kéékèèké la àwọn àwòrán èso Pomegiranate náà láàrin.

26. Agogo wúrà kan, àwòrán èso Pomegiranate kan, agogo wúrà kan, àwòrán èso Pomegiranate kan, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tò wọ́n yípo etí ẹ̀wù àwọ̀kanlẹ̀ náà, fún ṣíṣe iṣẹ́ alufaa gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.

27. Wọ́n fi aṣọ funfun dáradára dá ẹ̀wù meji fún Aaroni ati fún àwọn ọmọ rẹ̀,

28. wọ́n fi ṣe adé, ati fìlà ati ṣòkòtò.

29. Wọ́n fi aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́, ti aláwọ̀ aró, ti elése àlùkò ati aṣọ pupa tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí lára ṣe àmùrè gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.

30. Wọ́n fi ojúlówó wúrà ṣe ìgbátí adé mímọ́ náà, wọ́n sì kọ àkọlé kan sí ara rẹ̀ bí wọ́n ti ń kọ ọ́ sí ara òrùka èdìdì, pé, “Mímọ́ fún OLUWA.”

31. Wọ́n so aṣọ aláwọ̀ aró tẹ́ẹ́rẹ́ kan mọ́ ọn, láti máa fi so ó mọ́ etí adé náà gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.

32. Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo iṣẹ́ àgọ́ àjọ náà ṣe parí, àwọn ọmọ Israẹli ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.

33. Wọ́n sì gbé àgọ́ àjọ náà tọ Mose wá, àgọ́ náà ati gbogbo àwọn ohun èlò inú rẹ̀, àwọn ìkọ́ rẹ̀, àwọn àkànpọ̀ igi inú rẹ̀, àwọn igi ìdábùú inú rẹ̀, àwọn òpó rẹ̀, ati àwọn ìtẹ́lẹ̀ wọn;

Ka pipe ipin Ẹkisodu 39