Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 39:18-26 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Wọ́n mú etí kinni keji ẹ̀wọ̀n wúrà mejeeji, wọ́n so wọ́n mọ́ ojú ìdè wúrà ara ìgbàyà náà, wọ́n sì so wọ́n mọ́ èjìká efodu náà.

19. Lẹ́yìn náà wọ́n da òrùka wúrà meji, wọ́n sì dè wọ́n mọ́ etí kinni keji ìgbàyà náà, lọ́wọ́ inú ní ẹ̀gbẹ́ tí ó kan ara efodu.

20. Wọ́n sì da òrùka wúrà meji mìíràn, wọ́n dè wọ́n mọ́ ìsàlẹ̀ èjìká efodu náà níwájú, lókè ibi tí ó ti so pọ̀ mọ́ àmùrè rẹ̀.

21. Òrùka aṣọ ìgbàyà yìí ni wọ́n fi dè é mọ́ òrùka ara efodu pẹlu aṣọ aláwọ̀ aró tẹ́ẹ́rẹ́ kan, kí ó lè sùn lé àmùrè efodu náà tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí lára, kí ìgbàyà náà má baà tú kúrò lára efodu, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.

22. Ó fi aṣọ aláwọ̀ aró rán ẹ̀wù àwọ̀kanlẹ̀ sí efodu náà,

23. wọ́n yọ ọrùn sí ẹ̀wù àwọ̀kanlẹ̀ náà bí ọrùn ẹ̀wù gan-an, wọ́n sì fi aṣọ tẹ́ẹ́rẹ́ gbá a yípo kí ó má baà ya.

24. Wọ́n fi aṣọ aláwọ̀ aró, ti elése àlùkò, ati aṣọ pupa ati aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ ṣe àwòrán èso Pomegiranate sí etí ẹ̀wù àwọ̀kanlẹ̀ náà nísàlẹ̀.

25. Wọ́n sì fi agogo ojúlówó wúrà kéékèèké la àwọn àwòrán èso Pomegiranate náà láàrin.

26. Agogo wúrà kan, àwòrán èso Pomegiranate kan, agogo wúrà kan, àwòrán èso Pomegiranate kan, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tò wọ́n yípo etí ẹ̀wù àwọ̀kanlẹ̀ náà, fún ṣíṣe iṣẹ́ alufaa gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 39