Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 39:16-23 BIBELI MIMỌ (BM)

16. Wọ́n ṣe ojú ìdè wúrà meji, ati òrùka wúrà meji, wọ́n fi òrùka wúrà mejeeji sí etí kinni keji ìgbàyà náà.

17. Wọ́n ti àwọn ẹ̀wọ̀n wúrà mejeeji náà bọ àwọn òrùka mejeeji tí wọ́n wà ní etí kinni keji ìgbàyà náà.

18. Wọ́n mú etí kinni keji ẹ̀wọ̀n wúrà mejeeji, wọ́n so wọ́n mọ́ ojú ìdè wúrà ara ìgbàyà náà, wọ́n sì so wọ́n mọ́ èjìká efodu náà.

19. Lẹ́yìn náà wọ́n da òrùka wúrà meji, wọ́n sì dè wọ́n mọ́ etí kinni keji ìgbàyà náà, lọ́wọ́ inú ní ẹ̀gbẹ́ tí ó kan ara efodu.

20. Wọ́n sì da òrùka wúrà meji mìíràn, wọ́n dè wọ́n mọ́ ìsàlẹ̀ èjìká efodu náà níwájú, lókè ibi tí ó ti so pọ̀ mọ́ àmùrè rẹ̀.

21. Òrùka aṣọ ìgbàyà yìí ni wọ́n fi dè é mọ́ òrùka ara efodu pẹlu aṣọ aláwọ̀ aró tẹ́ẹ́rẹ́ kan, kí ó lè sùn lé àmùrè efodu náà tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí lára, kí ìgbàyà náà má baà tú kúrò lára efodu, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.

22. Ó fi aṣọ aláwọ̀ aró rán ẹ̀wù àwọ̀kanlẹ̀ sí efodu náà,

23. wọ́n yọ ọrùn sí ẹ̀wù àwọ̀kanlẹ̀ náà bí ọrùn ẹ̀wù gan-an, wọ́n sì fi aṣọ tẹ́ẹ́rẹ́ gbá a yípo kí ó má baà ya.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 39