Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 36:6-18 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Mose bá pàṣẹ, wọ́n sì kéde yí gbogbo àgọ́ ká, pé kí ẹnikẹ́ni, kì báà ṣe ọkunrin, tabi obinrin, má wulẹ̀ ṣòpò láti mú ọrẹ wá fún kíkọ́ ibi mímọ́ náà mọ́. Wọ́n sì dá àwọn eniyan náà lẹ́kun pé kí wọ́n má mú ọrẹ wá mọ́;

7. nítorí pé ohun tí wọ́n ti mú wá ti tó, ó tilẹ̀ ti pọ̀jù fún ohun tí wọ́n nílò láti fi ṣe iṣẹ́ náà.

8. Àwọn tí wọ́n mọ iṣẹ́ jù lára àwọn òṣìṣẹ́ náà kọ́ ibi mímọ́ náà pẹlu aṣọ títa mẹ́wàá. Aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ ati aṣọ ẹlẹ́pa ati elése àlùkò ati aṣọ pupa fòò ni wọ́n fi ṣe àwọn aṣọ títa náà, wọ́n sì ya àwòrán kerubu sára rẹ̀; wọn fi dárà sí i.

9. Gígùn aṣọ títa kọ̀ọ̀kan jẹ́ igbọnwọ mejidinlọgbọn, ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹrin, gbogbo wọn rí bákan náà.

10. Ó rán marun-un ninu àwọn aṣọ títa náà pọ̀, ó sì rán marun-un yòókù pọ̀ lọ́tọ̀ọ̀tọ̀.

11. Ó mú aṣọ aláwọ̀ aró, wọ́n fi rán ojóbó sára aṣọ títa tí ó kángun síta ninu àránpọ̀ aṣọ kinni, wọ́n sì tún rán ojóbó sára aṣọ títa tó kángun síta ninu àránpọ̀ aṣọ keji bákan náà.

12. Aadọta ojóbó ni wọ́n rán mọ́ àránpọ̀ aṣọ títa kinni, aadọta ojóbó náà ni wọ́n sì rán mọ́ etí àránpọ̀ aṣọ títa keji, àwọn ojóbó náà dojú kọ ara wọn.

13. Wọ́n ṣe aadọta ìkọ́ wúrà, wọ́n fi àwọn ìkọ́ náà kọ́ àránpọ̀ aṣọ títa náà mọ́ ara wọn, bẹ́ẹ̀ ni àgọ́ náà ṣe di odidi kan.

14. Wọ́n tún mú aṣọ títa mọkanla tí wọ́n fi irun ewúrẹ́ ṣe, wọ́n rán an pọ̀, wọ́n fi ṣe ìbòrí sí àgọ́ náà.

15. Gígùn aṣọ kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọgbọ̀n igbọnwọ, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹrin; bákan náà ni òòró ati ìbú àwọn aṣọ mọkọọkanla.

16. Wọ́n rán marun-un pọ̀ ninu àwọn aṣọ títa náà, lẹ́yìn náà ó rán mẹfa yòókù pọ̀.

17. Wọ́n ṣe aadọta ojóbó sára èyí tí ó kángun síta lára àránpọ̀ aṣọ kinni, ati èyí tí ó kángun síta lára àránpọ̀ aṣọ keji.

18. Wọ́n sì ṣe aadọta ìkọ́ idẹ láti fi mú aṣọ àgọ́ náà papọ̀ kí ó lè di ẹyọ kan ṣoṣo.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 36