Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 36:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. “Kí Besaleli, ati Oholiabu ati olukuluku àwọn tí OLUWA fún ní ìmọ̀ ati òye, láti ṣe èyíkéyìí ninu iṣẹ́ tí ó jẹmọ́ kíkọ́ ilé mímọ́ náà, ṣe é bí OLUWA ti pa á láṣẹ gan-an.”

2. Mose bá pe Besaleli ati Oholiabu, ati olukuluku àwọn tí OLUWA ti fún ní ìmọ̀ ati òye ati gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìfẹ́ sí iṣẹ́ náà láti wá bẹ̀rẹ̀ rẹ̀.

3. Àwọn òṣìṣẹ́ náà gba gbogbo àwọn ọrẹ àtinúwá tí àwọn ọmọ Israẹli mú wá láti fi ṣe iṣẹ́ àgọ́ mímọ́ náà lọ́wọ́ Mose. Àwọn eniyan ṣá tún ń mú ọrẹ àtinúwá yìí tọ Mose lọ ní àràárọ̀.

4. Wọ́n mú ọrẹ wá tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn tí wọn ń ṣe iṣẹ́ ibi mímọ́ náà tọ Mose lọ;

5. wọ́n sọ fún un pé, “Ohun tí àwọn eniyan náà mú wá ti pọ̀ ju ohun tí a nílò láti fi ṣe iṣẹ́ tí OLUWA pa láṣẹ fún wa.”

6. Mose bá pàṣẹ, wọ́n sì kéde yí gbogbo àgọ́ ká, pé kí ẹnikẹ́ni, kì báà ṣe ọkunrin, tabi obinrin, má wulẹ̀ ṣòpò láti mú ọrẹ wá fún kíkọ́ ibi mímọ́ náà mọ́. Wọ́n sì dá àwọn eniyan náà lẹ́kun pé kí wọ́n má mú ọrẹ wá mọ́;

7. nítorí pé ohun tí wọ́n ti mú wá ti tó, ó tilẹ̀ ti pọ̀jù fún ohun tí wọ́n nílò láti fi ṣe iṣẹ́ náà.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 36