Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 35:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Mose pe gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ, ó wí fún wọn pé, “Àwọn nǹkan tí OLUWA pa láṣẹ pé kí ẹ máa ṣe nìwọ̀nyí:

2. Ọjọ́ mẹfa ni kí ẹ máa fi ṣiṣẹ́, ṣugbọn kí ẹ ya ọjọ́ keje sọ́tọ̀ fún OLUWA bí ọjọ́ ìsinmi tí ó lọ́wọ̀; ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ ní ọjọ́ náà, pípa ni kí ẹ pa á.

3. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ dáná ní gbogbo ilé yín ní ọjọ́ ìsinmi.”

4. Mose sọ fún gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA pa láṣẹ, ó ní,

5. ‘Ẹ gba ọrẹ jọ fún OLUWA láàrin ara yín, ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́, lè mú ọrẹ wá fún OLUWA. Àwọn ọrẹ náà ni: wúrà, fadaka ati idẹ,

6. aṣọ aláwọ̀ aró, ti aláwọ̀ elése àlùkò, ati aṣọ pupa, aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́, ati irun ewúrẹ́;

7. awọ àgbò tí wọ́n ṣe ní àwọ̀ pupa ati awọ ewúrẹ́, igi akasia,

8. òróró ìtànná, àwọn èròjà fún òróró ìyàsímímọ́ ati fún turari olóòórùn dídùn,

Ka pipe ipin Ẹkisodu 35