Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 33:7-18 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Mose a máa pa àgọ́ àjọ sí òkèèrè, lẹ́yìn ibùdó àwọn ọmọ Israẹli, ó sì sọ ọ́ ní àgọ́ àjọ. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ní ohunkohun láti bèèrè lọ́dọ̀ OLUWA yóo lọ sí ibi àgọ́ àjọ náà, tí ó wà lẹ́yìn ibùdó àwọn ọmọ Israẹli.

8. Nígbàkúùgbà tí Mose bá ń lọ sí ibi àgọ́ àjọ, olukuluku á dúró lẹ́nu ọ̀nà àgọ́ rẹ̀, wọn a sì máa wò ó títí yóo fi wọ inú àgọ́ àjọ lọ.

9. Bí Mose bá ti wọ inú àgọ́ àjọ náà lọ, ìkùukùu náà á sọ̀kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òpó, a sì dúró lẹ́nu ọ̀nà àgọ́ náà. OLUWA yóo sì bá Mose sọ̀rọ̀.

10. Nígbà tí gbogbo àwọn eniyan bá sì rí ìkùukùu tí ó dàbí òpó yìí, lẹ́nu ọ̀nà àgọ́, gbogbo àwọn eniyan á dìde, olukuluku wọn á sì sin OLUWA ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ rẹ̀.

11. Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ṣe máa ń bá Mose sọ̀rọ̀ ní ojúkoojú, bí eniyan ṣe ń bá ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀. Nígbà tí Mose bá pada sí ibùdó, Joṣua, iranṣẹ rẹ̀, ọmọ Nuni, tí òun jẹ́ ọdọmọkunrin, kìí kúrò ninu àgọ́ àjọ.

12. Mose bá wí fún OLUWA pé, “Ṣebí ìwọ OLUWA ni o sọ pé kí n kó àwọn eniyan wọnyi wá, ṣugbọn o kò tíì fi ẹni tí o óo rán ṣìkejì mi hàn mí. Sibẹsibẹ, o wí pé, o mọ̀ mí o sì mọ orúkọ mi, ati pé mo ti rí ojurere rẹ.

13. Nítorí náà, mo bẹ̀ ọ́, bí inú rẹ bá dùn sí mi, fi ọ̀nà rẹ hàn mí, kí n lè mọ̀ ọ́, kí ǹ sì lè bá ojurere rẹ pàdé. Sì ranti pé àwọn eniyan rẹ ni àwọn eniyan wọnyi.”

14. OLUWA bá dá a lóhùn pé, “Ojú mi yóo máa bá ọ lọ, n óo sì fún ọ ní ìsinmi.”

15. Mose wí fún OLUWA pé, “Bí o kò bá ní bá wa lọ, má wulẹ̀ kó wa kúrò níhìn-ín.

16. Nítorí pé, báwo ni àwọn eniyan yóo ṣe mọ̀ pé, inú rẹ dùn sí èmi ati àwọn eniyan rẹ? Ṣebí bí o bá wà pẹlu wa bí a ti ń lọ ni a óo fi lè dá èmi ati àwọn eniyan rẹ mọ̀ yàtọ̀ sí gbogbo aráyé yòókù.”

17. OLUWA dá Mose lóhùn pé, “N óo ṣe ohun tí o wí, nítorí pé inú mi dùn sí ọ, mo sì mọ orúkọ rẹ.”

18. Mose dáhùn pé, “Mo bẹ̀ ọ́, fi ògo rẹ hàn mí.”

Ka pipe ipin Ẹkisodu 33