Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 33:11-23 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ṣe máa ń bá Mose sọ̀rọ̀ ní ojúkoojú, bí eniyan ṣe ń bá ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀. Nígbà tí Mose bá pada sí ibùdó, Joṣua, iranṣẹ rẹ̀, ọmọ Nuni, tí òun jẹ́ ọdọmọkunrin, kìí kúrò ninu àgọ́ àjọ.

12. Mose bá wí fún OLUWA pé, “Ṣebí ìwọ OLUWA ni o sọ pé kí n kó àwọn eniyan wọnyi wá, ṣugbọn o kò tíì fi ẹni tí o óo rán ṣìkejì mi hàn mí. Sibẹsibẹ, o wí pé, o mọ̀ mí o sì mọ orúkọ mi, ati pé mo ti rí ojurere rẹ.

13. Nítorí náà, mo bẹ̀ ọ́, bí inú rẹ bá dùn sí mi, fi ọ̀nà rẹ hàn mí, kí n lè mọ̀ ọ́, kí ǹ sì lè bá ojurere rẹ pàdé. Sì ranti pé àwọn eniyan rẹ ni àwọn eniyan wọnyi.”

14. OLUWA bá dá a lóhùn pé, “Ojú mi yóo máa bá ọ lọ, n óo sì fún ọ ní ìsinmi.”

15. Mose wí fún OLUWA pé, “Bí o kò bá ní bá wa lọ, má wulẹ̀ kó wa kúrò níhìn-ín.

16. Nítorí pé, báwo ni àwọn eniyan yóo ṣe mọ̀ pé, inú rẹ dùn sí èmi ati àwọn eniyan rẹ? Ṣebí bí o bá wà pẹlu wa bí a ti ń lọ ni a óo fi lè dá èmi ati àwọn eniyan rẹ mọ̀ yàtọ̀ sí gbogbo aráyé yòókù.”

17. OLUWA dá Mose lóhùn pé, “N óo ṣe ohun tí o wí, nítorí pé inú mi dùn sí ọ, mo sì mọ orúkọ rẹ.”

18. Mose dáhùn pé, “Mo bẹ̀ ọ́, fi ògo rẹ hàn mí.”

19. OLUWA sì dá Mose lóhùn pé, “N óo mú kí ẹwà mi kọjá níwájú rẹ; n óo sì pe orúkọ mímọ́ mi lójú rẹ, èmi ni OLUWA, èmi a máa yọ́nú sí àwọn tí ó bá wù mí, èmi a sì máa ṣàánú fún àwọn tí mo bá fẹ́.”

20. OLUWA ní, “O kò lè rí ojú mi nítorí pé eniyan kò lè rí ojú mi kí ó wà láàyè.”

21. OLUWA tún dáhùn pé, “Ibìkan wà, lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀dọ̀ mi, wá dúró lórí òkúta kan níbẹ̀.

22. Nígbà tí ògo mi bá ń kọjá lọ, n óo pa ọ́ mọ́ ninu ihò òkúta yìí, n óo sì fi ọwọ́ mi bò ọ́ lójú nígbà tí mo bá ń rékọjá.

23. Lẹ́yìn náà, n óo ká ọwọ́ mi kúrò, o óo sì rí àkẹ̀yìnsí mi, ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò lè rí ojú mi.”

Ka pipe ipin Ẹkisodu 33