Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 30:21-31 BIBELI MIMỌ (BM)

21. Dandan ni kí wọ́n fọ ọwọ́ ati ẹsẹ̀ wọn, kí wọ́n má baà kú. Èyí yóo di ìlànà fún wọn títí lae: fún òun ati arọmọdọmọ rẹ̀ ní gbogbo ìran wọn.”

22. Lẹ́yìn náà, OLUWA tún wí fún Mose pé,

23. “Mú ojúlówó àwọn nǹkan olóòórùn dídùn wọnyi kí o kó wọn jọ: ẹẹdẹgbẹta (500) ìwọ̀n ṣekeli òjíá olómi, ati aadọtaleerugba (250) ìwọ̀n ṣekeli sinamoni, ati aadọtaleerugba (250) ìwọ̀n ṣekeli igi olóòórùn dídùn kan tí ó dàbí èèsún,

24. ati ẹẹdẹgbẹta (500) ìwọ̀n ṣekeli kasia, ìwọ̀n ṣekeli ilé OLUWA ni kí wọ́n lò láti wọ̀n wọ́n. Lẹ́yìn náà, mú ìwọ̀n hini ojúlówó òróró olifi kan.

25. Pa gbogbo nǹkan wọnyi pọ̀, kí o fi ṣe òróró mímọ́ fún ìyàsímímọ́. Ṣe é bí àwọn ìpara olóòórùn dídùn, yóo jẹ́ òróró ìyàsímímọ́ fún OLUWA.

26. Ta òróró yìí sí ara àgọ́ àjọ, ati sí ara àpótí ẹ̀rí,

27. ati sí ara tabili, ati gbogbo àwọn ohun èlò orí rẹ̀, ati sí ara ọ̀pá fìtílà ati gbogbo àwọn ohun èlò rẹ̀, ati sí ara pẹpẹ turari,

28. ati sí ara pẹpẹ ẹbọ sísun, ati gbogbo àwọn ohun èlò rẹ̀, ati sí ara agbada omi, ati ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀.

29. Fi yà wọ́n sí mímọ́, kí wọ́n lè jẹ́ mímọ́ patapata; ohunkohun tí ó bá kàn wọ́n yóo sì di mímọ́.

30. Ta òróró yìí sí Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ lórí, kí o fi yà wọ́n sí mímọ́; kí wọ́n lè máa ṣe alufaa fún mi.

31. Sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé, ‘Òróró yìí ni yóo jẹ́ òróró ìyàsímímọ́ ní ìrandíran yín,

Ka pipe ipin Ẹkisodu 30