Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 30:20-25 BIBELI MIMỌ (BM)

20. Nígbà tí wọ́n bá ń wọ àgọ́ àjọ lọ, tabi nígbà tí wọ́n bá súnmọ́ ibi pẹpẹ láti ṣe iṣẹ́ alufaa wọn, láti rú ẹbọ sísun sí OLUWA; omi yìí ni wọ́n gbọdọ̀ fi fọ ọwọ́ ati ẹsẹ̀ wọn kí wọ́n má baà kú.

21. Dandan ni kí wọ́n fọ ọwọ́ ati ẹsẹ̀ wọn, kí wọ́n má baà kú. Èyí yóo di ìlànà fún wọn títí lae: fún òun ati arọmọdọmọ rẹ̀ ní gbogbo ìran wọn.”

22. Lẹ́yìn náà, OLUWA tún wí fún Mose pé,

23. “Mú ojúlówó àwọn nǹkan olóòórùn dídùn wọnyi kí o kó wọn jọ: ẹẹdẹgbẹta (500) ìwọ̀n ṣekeli òjíá olómi, ati aadọtaleerugba (250) ìwọ̀n ṣekeli sinamoni, ati aadọtaleerugba (250) ìwọ̀n ṣekeli igi olóòórùn dídùn kan tí ó dàbí èèsún,

24. ati ẹẹdẹgbẹta (500) ìwọ̀n ṣekeli kasia, ìwọ̀n ṣekeli ilé OLUWA ni kí wọ́n lò láti wọ̀n wọ́n. Lẹ́yìn náà, mú ìwọ̀n hini ojúlówó òróró olifi kan.

25. Pa gbogbo nǹkan wọnyi pọ̀, kí o fi ṣe òróró mímọ́ fún ìyàsímímọ́. Ṣe é bí àwọn ìpara olóòórùn dídùn, yóo jẹ́ òróró ìyàsímímọ́ fún OLUWA.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 30