Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 28:6-18 BIBELI MIMỌ (BM)

6. “Wọn yóo ṣe efodu wúrà, ati aṣọ aláwọ̀ aró, ati ti aláwọ̀ elése àlùkò, aláwọ̀ pupa ati aṣọ ọ̀gbọ̀ tí ó ní ìlà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́; wọn yóo sì ṣe iṣẹ́ ọnà sí i lára.

7. Kí wọ́n rán àgbékọ́ meji mọ́ etí rẹ̀ mejeeji, tí wọn yóo fi lè máa so ó pọ̀.

8. Irú aṣọ kan náà tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí lára ni kí wọ́n fi ṣe àmùrè rẹ̀. Iṣẹ́ ọnà kan náà ni kí wọ́n ṣe sí i lára pẹlu wúrà, aṣọ aláwọ̀ aró, aláwọ̀ elése àlùkò, aláwọ̀ pupa, ati aṣọ ọ̀gbọ̀ tí ó ní ìlà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́.

9. Mú òkúta onikisi meji, kí o sì kọ orúkọ àwọn ẹ̀yà Israẹli sí ara wọn.

10. Orúkọ ẹ̀yà mẹfa sára òkúta ekinni ati orúkọ ẹ̀yà mẹfa yòókù sára ekeji, kí o to àwọn orúkọ náà bí wọ́n ṣe bí wọn tẹ̀lé ara wọn.

11. Bí oníṣẹ́ ọnà wúrà ti máa ń kọ orúkọ sí ara òrùka èdìdì, ni kí o kọ orúkọ àwọn ọmọ Israẹli sí ara òkúta mejeeji, kí o sì fi wúrà ṣe ìtẹ́lẹ̀ wọn.

12. Lẹ́yìn náà, rán àwọn òkúta mejeeji mọ́ àwọn èjìká efodu náà, gẹ́gẹ́ bí òkúta ìrántí fún àwọn ọmọ Israẹli. Èyí yóo mú kí Aaroni máa mú orúkọ wọn wá siwaju OLUWA fún ìrántí.

13. O óo ṣe àwọn ìtẹ́lẹ̀ wúrà,

14. ati ẹ̀wọ̀n wúrà meji tí a lọ́ pọ̀ bí okùn, kí o sì so àwọn ẹ̀wọ̀n wúrà náà mọ́ àwọn ìtẹ́lẹ̀ wúrà náà.

15. “Ṣe ìgbàyà ìdájọ́, èyí tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà dáradára sí lára, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọnà ara efodu náà: wúrà, aṣọ aláwọ̀ aró, aláwọ̀ elése àlùkò, aláwọ̀ pupa ati aṣọ ọ̀gbọ̀ tí ó ní ìlà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́, ni kí o fi ṣe é.

16. Bákan náà ni ìbú ati òòró rẹ̀ yóo rí, ìṣẹ́po meji ni yóo jẹ́, ìbú ati òòró rẹ̀ yóo sì jẹ́ ìká kọ̀ọ̀kan.

17. To òkúta olówó iyebíye sí ara rẹ̀ ní ẹsẹ̀ mẹrin, kí ẹsẹ̀ àkọ́kọ́ jẹ́ òkúta sadiu, ati òkúta topasi, ati òkúta kabọnku.

18. Kí ẹsẹ̀ keji jẹ́ òkúta emeradi, ati òkúta safire, ati òkúta dayamọndi.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 28