Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 28:31-43 BIBELI MIMỌ (BM)

31. “O óo fi aṣọ aláwọ̀ aró rán ẹ̀wù àwọ̀kanlẹ̀ sí efodu náà.

32. Yọ ọrùn sí ẹ̀wù náà, kí o sì fi aṣọ bí ọ̀já tẹ́ẹ́rẹ́ gbá a lọ́rùn yípo, bí wọ́n ti máa ń fi aṣọ tẹ́ẹ́rẹ́ gbá ọrùn ẹ̀wù, kí ó má baà ya.

33. Fi aṣọ aláwọ̀ aró, ati ti elése àlùkò, ati aṣọ pupa ya àwòrán èso pomegiranate sí etí ẹ̀wù àwọ̀kanlẹ̀ náà nísàlẹ̀, sì fi agogo ojúlówó wúrà kéékèèké kọ̀ọ̀kan la àwọn àwòrán èso pomegiranate náà láàrin, yípo etí àwọ̀kanlẹ̀ efodu náà, nísàlẹ̀.

34. Agogo wúrà kan, àwòrán èso pomegiranate kan, bẹ́ẹ̀ ni kí o tò wọ́n sí etí ẹ̀wù àwọ̀kanlẹ̀ efodu náà.

35. Èyí ni Aaroni yóo máa wọ̀ nígbà tí ó bá ń ṣe iṣẹ́ alufaa rẹ̀, yóo sì máa gbọ́ ìró rẹ̀ nígbà tí ó bá ń wọ ibi mímọ́ lọ níwájú OLUWA ati ìgbà tí ó bá ń jáde, kí ó má baà kú.

36. “Fi ojúlówó wúrà ṣe ìgbátí kan kí o sì kọ àkọlé sí i gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sí ara òrùka èdìdì, àkọlé náà nìyí: ‘Mímọ́ fún OLUWA.’

37. Fi aṣọ tẹ́ẹ́rẹ́, aláwọ̀ aró dè é mọ́ fìlà alufaa níwájú.

38. Nígbà tí Aaroni bá ń rú ẹbọ mímọ́, tí àwọn ọmọ Israẹli ti yà sọ́tọ̀ fún èmi OLUWA, kinní bí àwo pẹrẹsẹ yìí yóo máa wà níwájú orí rẹ̀, kí wọ́n lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ mi.

39. “Fi aṣọ ọ̀gbọ̀ tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí dá ẹ̀wù fún Aaroni, kí o fi aṣọ ọ̀gbọ̀ rán fìlà rẹ̀ pẹlu, lẹ́yìn náà rán àmùrè tí a ṣe iṣẹ́ ọnà sí lára fún un.

40. “Rán ẹ̀wù ati àmùrè, ati fìlà fún àwọn ọmọ Aaroni fún ògo ati ẹwà.

41. Gbé àwọn ẹ̀wù náà wọ Aaroni arakunrin rẹ, ati àwọn ọmọ rẹ̀, kí o sì ta òróró sí wọn lórí láti yà wọ́n sọ́tọ̀ ati láti yà wọ́n sí mímọ́, kí wọ́n lè máa ṣe iṣẹ́ alufaa fún mi.

42. Fi aṣọ ọ̀gbọ̀ dá ṣòkòtò fún wọn; láti máa fi bo ìhòòhò wọn, láti ìbàdí títí dé itan.

43. Kí Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ máa wọ ṣòkòtò náà, nígbà tí wọ́n bá wọ inú àgọ́ àjọ lọ, tabi nígbà tí wọ́n bá súnmọ́ ibi pẹpẹ láti ṣe iṣẹ́ alufaa ni ibi mímọ́, kí wọ́n má baà dẹ́ṣẹ̀, kí wọ́n sì kú. Títí laelae ni òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ yóo máa pa ìlànà yìí mọ́.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 28