Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 27:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. “Igi akasia ni kí o fi ṣe pẹpẹ, kí ó gùn ní ìwọ̀n igbọnwọ marun-un, kí ó sì fẹ̀ ní ìwọ̀n igbọnwọ marun-un; kí òòró ati ìbú pẹpẹ náà rí bákan náà, kí ó sì ga ní ìwọ̀n igbọnwọ mẹta.

2. Yọ ìwo kọ̀ọ̀kan sí igun rẹ̀ mẹrẹẹrin, àṣepọ̀ ni kí o ṣe àwọn ìwo náà mọ́ pẹpẹ, kí o sì yọ́ idẹ bo gbogbo rẹ̀.

3. Fi idẹ ṣe ìkòkò láti máa kó eérú orí pẹpẹ sí, fi idẹ ṣe ọkọ́, àwo kòtò, ọ̀kọ̀ tí wọ́n fi ń gún ẹran ẹbọ ati àwo ìfọnná, idẹ ni kí o fi ṣe gbogbo àwọn ohun èlò pẹpẹ náà.

4. Idẹ ni kí o fi ṣe asẹ́ ààrò rẹ̀, kí o sì ṣe òrùka idẹ mẹrin, ọ̀kọ̀ọ̀kan sí igun mẹrẹẹrin asẹ́ náà.

5. Ti asẹ́ idẹ náà bọ abẹ́ etí pẹpẹ, tí yóo fi jẹ́ pé asẹ́ náà yóo dé agbede meji pẹpẹ náà sísàlẹ̀.

6. Fi igi akasia ṣe ọ̀pá pẹpẹ, kí o sì yọ́ idẹ bo ọ̀pá náà.

7. Kí o ti àwọn ọ̀pá náà bọ àwọn òrùka ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ, tí ọ̀pá yóo fi wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji pẹpẹ náà nígbà tí wọ́n bá fẹ́ gbé e.

8. Fi pákó ṣe pẹpẹ náà, kí o sì jẹ́ kí ó jin kòtò, bí mo ti fi hàn ọ́ ní orí òkè, bẹ́ẹ̀ gan-an ni kí o ṣe é.

9. “Ṣe àgbàlá kan sinu àgọ́ náà. Aṣọ ọ̀gbọ̀ ni kí o fi ṣe aṣọ títa apá gúsù àgbàlá náà, kí gígùn rẹ̀ jẹ́ ọgọrun-un igbọnwọ,

Ka pipe ipin Ẹkisodu 27