Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 26:4-15 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Fi aṣọ aláwọ̀ aró ṣe ojóbó sí etí ẹ̀gbẹ́ tí ó wà ní òde ninu aṣọ àránpọ̀ kọ̀ọ̀kan.

5. Aadọta ojóbó ni kí o ṣe sí àránpọ̀ aṣọ kinni, lẹ́yìn náà ṣe aadọta ojóbó sí àránpọ̀ aṣọ keji, kí àwọn ojóbó náà lè kọ ojú sí ara wọn.

6. Lẹ́yìn náà, ṣe aadọta ìkọ́ wúrà, kí o fi kọ́ àwọn ojóbó àránpọ̀ aṣọ mejeeji, kí àgọ́ náà lè dúró ní odidi kan ṣoṣo.

7. “Fi awẹ́ aṣọ mọkanla tí wọ́n fi irun ewúrẹ́ ṣe, ṣe ìbòrí kan fún àgọ́ náà.

8. Kí gígùn ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu aṣọ náà jẹ́ ọgbọ̀n igbọnwọ, kí fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹrin, kí àwọn aṣọ mọkọọkanla gùn bákan náà, kí wọ́n sì fẹ̀ bákan náà.

9. Rán marun-un ninu àwọn aṣọ náà pọ̀, lẹ́yìn náà, rán mẹfa yòókù pọ̀, kí o ṣẹ́ aṣọ kẹfa po bo iwájú àgọ́ náà.

10. Ṣe aadọta ojóbó sí awẹ́ tí ó parí àránpọ̀ aṣọ kinni, kí o sì ṣe aadọta ojóbó sí etí awẹ́ tí ó parí aṣọ àránpọ̀ keji.

11. Fi idẹ ṣe aadọta ìkọ́, kí o sì fi wọ́n kọ́ àwọn ojóbó náà, láti mú àwọn àránpọ̀ aṣọ mejeeji náà papọ̀ kí wọ́n lè jẹ́ ìbòrí kan.

12. Jẹ́ kí ìdajì awẹ́ tí ó kù ṣẹ́ bo ẹ̀yìn àgọ́ náà.

13. Jẹ́ kí igbọnwọ kọ̀ọ̀kan tí ó kù ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji àránpọ̀ aṣọ náà ṣẹ́ bo ẹ̀gbẹ́ kinni keji àgọ́ náà.

14. “Lẹ́yìn náà, fi awọ àgbò tí a ṣe ní pupa, ati awọ ewúrẹ́ tí a ṣe dáradára, ṣe ìbòrí keji fún àgọ́ náà.

15. “Igi akasia ni kí o fi ṣe àwọn òpó àgọ́ náà,

Ka pipe ipin Ẹkisodu 26