Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 24:13-18 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Mose bá gbéra, òun ati Joṣua iranṣẹ rẹ̀, ó gun orí òkè Ọlọrun lọ.

14. Ó sọ fún àwọn àgbààgbà pé, “Ẹ dúró níhìn-ín dè wá títí a óo fi pada wá bá yín. Aaroni ati Huri wà pẹlu yín, bí ẹnikẹ́ni bá ní àríyànjiyàn kan, kí ó kó o tọ̀ wọ́n lọ.”

15. Mose bá gun orí òkè náà lọ, ìkùukùu sì bo orí òkè náà.

16. Ògo OLUWA sọ̀kalẹ̀ sórí òkè Sinai, ìkùukùu sì bò ó fún ọjọ́ mẹfa, ní ọjọ́ keje, OLUWA pe Mose láti inú ìkùukùu náà.

17. Lójú àwọn eniyan Israẹli, ìrísí ògo OLUWA lórí òkè náà dàbí iná ńlá tí ń jóni ní àjórun.

18. Mose wọ inú ìkùukùu náà lọ, ó gun orí òkè náà, ó sì wà níbẹ̀ fún ogoji ọjọ́, tọ̀sán-tòru.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 24