Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 21:33-36 BIBELI MIMỌ (BM)

33. “Bí ẹnìkan bá gbẹ́ kòtò sílẹ̀, tí kò bá bò ó, tabi tí ó gbẹ́ kòtò tí kò sì dí i, bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tabi mààlúù bá já sinu kòtò yìí, tí ó sì kú,

34. ẹni tí ó gbẹ́ kòtò yìí gbọdọ̀ san owó mààlúù tabi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà fún ẹni tí ó ni ín, òkú ẹran yìí yóo sì di ti ẹni tí ó gbẹ́ kòtò.

35. Bí mààlúù ẹnìkan bá pa ti ẹlòmíràn, àwọn mejeeji yóo ta mààlúù tí ó jẹ́ ààyè, wọn yóo pín owó rẹ̀, wọn yóo sì pín òkú mààlúù náà pẹlu.

36. Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé mààlúù yìí ti máa ń kàn tẹ́lẹ̀, tí ẹni tí ó ni ín kò sì mú un so, yóo fi mààlúù mìíràn rọ́pò èyí tí mààlúù rẹ̀ pa, òkú mààlúù yóo sì di tirẹ̀.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 21