Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 2:21-25 BIBELI MIMỌ (BM)

21. Mose gbà láti máa gbé ọ̀dọ̀ ọkunrin náà, ó bá fún un ní Sipora, ọ̀kan ninu àwọn ọmọbinrin rẹ̀ láti fi ṣe aya.

22. Ó bí ọmọkunrin kan, ó sì sọ ọmọ náà ní Geriṣomu, ó wí pé, “Mo jẹ́ àtìpó ní ilẹ̀ àjèjì.”

23. Lẹ́yìn ọpọlọpọ ọdún, ọba Ijipti kú, àwọn ọmọ Israẹli sì ń kérora ní oko ẹrú tí wọ́n wà, wọ́n kígbe fún ìrànlọ́wọ́. Igbe tí wọn ń ké ní oko ẹrú sì gòkè tọ OLUWA lọ.

24. Ọlọrun gbọ́ ìkérora wọn, ó sì ranti majẹmu tí ó bá Abrahamu, ati Isaaki, ati Jakọbu dá.

25. Ọlọrun bojú wo àwọn eniyan Israẹli, ó sì rí irú ipò tí wọ́n wà.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 2