Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 11:4-10 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Mose bá sọ fún Farao pé, “OLUWA ní, nígbà tí ó bá di ọ̀gànjọ́ òru, òun yóo la ilẹ̀ Ijipti kọjá,

5. gbogbo àkọ́bí ní ilẹ̀ Ijipti ni yóo sì kú. Bẹ̀rẹ̀ láti orí àkọ́bí Farao, tí ó jókòó lórí ìtẹ́, títí kan àkọ́bí iranṣẹbinrin tí ń lọ ọkà, ati àkọ́bí gbogbo ẹran ọ̀sìn.

6. Ariwo ẹkún ńlá yóo sọ ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti, irú èyí tí kò ṣẹlẹ̀ rí, tí kò sì tún ní sí irú rẹ̀ mọ́.

7. Ṣugbọn ajá kò tilẹ̀ ní gbó ẹnikẹ́ni tabi ẹran ọ̀sìn kan, jákèjádò ààrin àwọn ọmọ Israẹli; kí ẹ lè mọ̀ pé OLUWA fi ìyàtọ̀ sí ààrin àwọn ará Ijipti ati àwọn ọmọ Israẹli.

8. Gbogbo àwọn ẹmẹ̀wà rẹ wọnyi yóo sì tọ̀ mí wá, wọn yóo fi orí balẹ̀ fún mi, wọn yóo wí pé kí n máa lọ, èmi ati gbogbo àwọn eniyan mi! Lẹ́yìn náà ni n óo jáde lọ.” Mose bá fi tìbínú-tìbínú jáde kúrò níwájú Farao.

9. Lẹ́yìn náà OLUWA sọ fún Mose pé, “Farao kò ní gba ọ̀rọ̀ rẹ, kí iṣẹ́ ìyanu mi baà lè di pupọ ní ilẹ̀ Ijipti.”

10. Mose ati Aaroni ṣe gbogbo iṣẹ́ ìyanu tí wọn ṣe níwájú Farao, ṣugbọn OLUWA sì mú kí ọkàn Farao le, kò sì jẹ́ kí àwọn eniyan Israẹli lọ kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 11