Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 11:1-5 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nígbà tí ó yá, OLUWA sọ fún Mose pé, “Ó ku ìyọnu kan péré, tí n óo mú bá Farao ati ilẹ̀ Ijipti, lẹ́yìn náà yóo jẹ́ kí ẹ lọ. Nígbà tí ó bá gbà kí ẹ lọ, òun fúnra rẹ̀ ni yóo tì yín jáde patapata.

2. Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kí olukuluku tọ aládùúgbò rẹ̀ lọ, ati ọkunrin ati obinrin wọn, kí wọ́n lọ tọrọ nǹkan ọ̀ṣọ́ fadaka ati ti wúrà.”

3. OLUWA jẹ́ kí àwọn eniyan Israẹli bá ojurere àwọn ará Ijipti pàdé, ati pé àwọn ará Ijipti ati àwọn ẹmẹ̀wà Farao ati àwọn eniyan rẹ̀ ka Mose kún eniyan pataki.

4. Mose bá sọ fún Farao pé, “OLUWA ní, nígbà tí ó bá di ọ̀gànjọ́ òru, òun yóo la ilẹ̀ Ijipti kọjá,

5. gbogbo àkọ́bí ní ilẹ̀ Ijipti ni yóo sì kú. Bẹ̀rẹ̀ láti orí àkọ́bí Farao, tí ó jókòó lórí ìtẹ́, títí kan àkọ́bí iranṣẹbinrin tí ń lọ ọkà, ati àkọ́bí gbogbo ẹran ọ̀sìn.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 11