Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 31:20-27 BIBELI MIMỌ (BM)

20. Nítorí pé, nígbà tí mo bá kó wọn wọ ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati oyin, tí mo ti búra pé n óo fún àwọn baba wọn; nígbà tí wọ́n bá jẹ, tí wọ́n yó tán, tí wọ́n sì sanra, wọn óo yipada sọ́dọ̀ àwọn oriṣa, wọn óo sì máa bọ wọ́n. Wọn óo kọ̀ mí sílẹ̀, wọn óo sì da majẹmu mi.

21. Nígbà tí ọpọlọpọ ibi ati wahala bá dé bá wọn, orin yìí ni yóo jẹ́ ẹ̀rí fún wọn (nítorí pé arọmọdọmọ wọn yóo máa kọ ọ́, wọn kò sì ní gbàgbé rẹ̀); nítorí pé mo mọ ète tí wọn ń pa, kí ó tilẹ̀ tó di pé mo mú wọn wọ ilẹ̀ tí mo búra láti fún wọn.”

22. Mose bá kọ orin yìí ní ọjọ́ náà-gan an, ó sì kọ́ àwọn ọmọ Israẹli.

23. OLUWA fi iṣẹ́ lé Joṣua ọmọ Nuni lọ́wọ́, ó ní, “Múra gírí kí o sì mú ọkàn gidigidi, nítorí ìwọ ni o óo kó àwọn ọmọ Israẹli wọ ilẹ̀ tí mo ti búra láti fún wọn. N óo wà pẹlu rẹ.”

24. Nígbà tí Mose kọ gbogbo ohun tí ó wà ninu ìwé òfin yìí tán patapata,

25. ó pàṣẹ fún àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n ru àpótí majẹmu OLUWA,

26. ó ní, “Ẹ fi ìwé òfin yìí sí ẹ̀gbẹ́ àpótí majẹmu OLUWA Ọlọrun yín, kí ó wà níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí pẹlu yín;

27. nítorí mo mọ̀ pé ọlọ̀tẹ̀ ati olóríkunkun ni yín; nígbà tí mo wà láàyè pẹlu yín lónìí, ẹ̀ ń ṣọ̀tẹ̀ sí OLUWA, kí á má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ìgbà tí mo bá kú tán.

Ka pipe ipin Diutaronomi 31