Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 26:3-9 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Tọ alufaa tí ó wà lẹ́nu iṣẹ́ ní àkókò náà lọ, kí o sì wí fún un pé, ‘Mò ń wí fún OLUWA Ọlọrun mi lónìí pé, mo ti dé ilẹ̀ tí ó ti búra fún àwọn baba wa láti fún wa.’

4. “Alufaa yóo gba agbọ̀n èso náà ní ọwọ́ rẹ, yóo sì gbé e kalẹ̀ níwájú pẹpẹ OLUWA Ọlọrun rẹ.

5. Lẹ́yìn náà, o óo wí báyìí níwájú OLUWA Ọlọrun rẹ pé, ‘Ará Aramea, alárìnká, ni baba ńlá mi, ó lọ sí ilẹ̀ Ijipti, ó sì jẹ́ àlejò níbẹ̀. Wọn kò pọ̀ rárá tẹ́lẹ̀, ṣugbọn níbẹ̀ ni wọ́n ti di pupọ, wọ́n sì di orílẹ̀-èdè ńlá, tí ó lágbára, tí ó sì lókìkí.

6. Àwọn ará Ijipti lò wá ní ìlò ìkà, wọ́n pọ́n wa lójú, wọ́n sì mú wa sìn bí ẹrú.

7. A bá kígbe pe OLUWA Ọlọrun àwọn baba wa; ó gbọ́ ohùn wa, ó rí ìpọ́njú, ati ìṣẹ́, ati ìjìyà wa.

8. OLUWA fi agbára rẹ̀ kó wa jáde láti Ijipti, pẹlu àwọn iṣẹ́ àmì ati iṣẹ́ ìyanu.

9. Ó kó wa wá sí ìhín, ó sì fún wa ní ilẹ̀ yìí; ilẹ̀ tí ó ní ọ̀rá tí ó kún fún wàrà ati oyin.

Ka pipe ipin Diutaronomi 26