Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 19:1-14 BIBELI MIMỌ (BM)

1. “Nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá pa àwọn orílẹ̀-èdè tí yóo fun yín ní ilẹ̀ wọn run, tí ẹ bá gba ilẹ̀ wọn, tí ẹ sì ń gbé inú àwọn ìlú wọn, ati ilé wọn,

2. ẹ ya ìlú mẹta sọ́tọ̀ fún ara yín ní ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín.

3. Ẹ pín ilẹ̀ náà sí agbègbè mẹta, kí ẹ sì la ọ̀nà mẹta wọ inú àwọn ìlú náà. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn ìlú mẹtẹẹta tí ẹ yà sọ́tọ̀ gbọdọ̀ wà ní agbègbè kọ̀ọ̀kan. Ẹ óo sì ṣí àwọn ọ̀nà tí ó wọ ìlú wọnyi kí ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣèèṣì paniyan lè tètè sálọ sibẹ.

4. Èyí wà fún anfaani ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣèèṣì paniyan. Bí ẹnìkan bá ṣèèṣì pa aládùúgbò rẹ̀ láìjẹ́ pé wọ́n ti ń bá ara wọn ṣe ọ̀tá tẹ́lẹ̀, bí ó bá sálọ sí èyíkéyìí ninu àwọn ìlú náà, yóo gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là.

5. Bí àpẹẹrẹ, bí ẹnìkan bá lọ sinu igbó pẹlu aládùúgbò rẹ̀ láti gé igi, bí ó ti ń fi àáké gé igi lọ́wọ́, bí irin àáké náà bá yọ, tí ó lọ bá aládùúgbò rẹ̀, tí ó sì pa á; irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè sálọ sí ọ̀kan ninu àwọn ìlú náà, kí ó sì gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là.

6. Kí ó má jẹ́ pé, nígbà tí ẹni tí yóo gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ ẹni tí ó ṣèèṣì pa bá ń lé e lọ pẹlu ibinu, bí ibi tí yóo sá àsálà lọ bá jìnnà jù, yóo bá a, yóo sì pa á; bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò yẹ kí wọ́n pa ẹni tí ó ṣèèṣì paniyan yìí, níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé òun ati aládùúgbò rẹ̀ kìí ṣe ọ̀tá tẹ́lẹ̀.

7. Nítorí náà ni mo fi pàṣẹ fun yín pé, ẹ níláti ya ìlú mẹta sọ́tọ̀.

8. “Bí OLUWA Ọlọrun yín bá sì mú kí ilẹ̀ yín tóbi síi gẹ́gẹ́ bí ó ti búra fún àwọn baba yín, tí ó bá fun yín ní gbogbo ilẹ̀ tí ó ṣèlérí fún àwọn baba yín,

9. bí ẹ bá lè pa gbogbo òfin rẹ̀ tí mo fun yín lónìí mọ́, tí ẹ fẹ́ràn OLUWA Ọlọrun yín, tí ẹ sì ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀, nígbà náà, ẹ tún fi ìlú mẹta mìíràn kún àwọn ìlú mẹta ti àkọ́kọ́.

10. Kí ẹnikẹ́ni má baà ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ní ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín láti jogún, kí ẹ̀bi ìtàjẹ̀sílẹ̀ má baà wà lórí yín.

11. “Ṣugbọn bí ẹnikẹ́ni bá kórìíra aládùúgbò rẹ̀, tí ó bá ba dè é, tí ó mọ̀ọ́nmọ̀ pa á, tí ó sì sálọ sí ọ̀kan ninu àwọn ìlú wọnyi,

12. kí àwọn àgbààgbà ìlú rán ni lọ mú ẹni náà wá, kí wọ́n sì fi lé ẹni tí yóo gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ ẹni tí ó pa lọ́wọ́, kí ó lè pa ẹni tí ó mọ̀ọ́nmọ̀ paniyan yìí.

13. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣàánú rẹ̀ rárá, ṣugbọn ẹ níláti mú ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ kúrò láàrin Israẹli, kí ó lè dára fun yín.

14. “Ninu ogún tìrẹ tí ó bá kàn ọ́ ninu ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín láti gbà, o kò gbọdọ̀ sún ohun tí àwọn baba ńlá rẹ bá fi pààlà ilẹ̀.

Ka pipe ipin Diutaronomi 19