Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 16:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. “Ẹ máa ranti láti máa ṣe àjọ̀dún àjọ ìrékọjá fún OLUWA Ọlọrun yín ninu oṣù Abibu nítorí ninu oṣù Abibu ni ó kó yín jáde ní ilẹ̀ Ijipti, lálẹ́.

2. Ẹ níláti máa rú ẹbọ àjọ ìrékọjá sí OLUWA Ọlọrun yín láti inú agbo mààlúù yín, tabi agbo aguntan yín, níbi tí ó bá yàn pé kí ẹ ti máa sin òun.

3. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ burẹdi tí ó ní ìwúkàrà ninu pẹlu ẹbọ náà; ọjọ́ meje ni ẹ óo fi jẹ ẹ́ pẹlu burẹdi tí kò ní ìwúkàrà. Oúnjẹ náà jẹ́ oúnjẹ ìpọ́njú, nítorí pé ìkánjú ni ẹ fi jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti; ẹ óo sì lè máa ranti ọjọ́ náà tí ẹ kúrò ní ilẹ̀ Ijipti ní gbogbo ọjọ́ ayé yín.

4. Wọn kò gbọdọ̀ bá ìwúkàrà lọ́wọ́ yín, ati ní gbogbo agbègbè yín, fún ọjọ́ meje. Ẹran tí ẹ bá fi rúbọ kò gbọdọ̀ ṣẹ́kù ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kinni, títí di òwúrọ̀ ọjọ́ keji.

5. “Ẹ kò gbọdọ̀ rú ẹbọ àjọ ìrékọjá láàrin èyíkéyìí ninu àwọn ìlú tí OLUWA Ọlọrun yín yóo fi fun yín.

6. Àfi ibi tí OLUWA Ọlọrun yín bá yàn pé kí ẹ ti máa sin òun, níbẹ̀ ni ẹ ti gbọdọ̀ máa rú ẹbọ àjọ ìrékọjá ní ìrọ̀lẹ́, nígbà tí oòrùn ń lọ wọ̀ ní àkókò tí ẹ jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti.

7. Bíbọ̀ ni kí ẹ bọ̀ ọ́, kí ẹ jẹ ẹ́ ní ibi tí OLUWA Ọlọrun yín bá yàn pé kí ẹ ti máa jọ́sìn, nígbà tí ó bá sì di òwúrọ̀ ẹ óo pada lọ sinu àgọ́ yín.

Ka pipe ipin Diutaronomi 16