Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 10:6-15 BIBELI MIMỌ (BM)

6. (Àwọn eniyan Israẹli rìn láti Beeroti Benejaakani lọ sí Mosera, ibẹ̀ ni Aaroni kú sí, tí wọ́n sì sin ín sí. Eleasari ọmọ rẹ̀ sì ń ṣe iṣẹ́ alufaa dípò rẹ̀.

7. Wọ́n gbéra láti ibẹ̀, wọ́n lọ sí Gudigoda. Láti Gudigoda, wọ́n lọ sí Jotibata, ilẹ̀ tí ó kún fún ọpọlọpọ odò tí ń ṣàn.

8. Ní àkókò yìí, OLUWA ya àwọn ẹ̀yà Lefi sọ́tọ̀ láti máa gbé Àpótí Majẹmu OLUWA, ati láti máa dúró níwájú OLUWA láti ṣe iṣẹ́ ìsìn, ati láti máa yin orúkọ rẹ̀, títí di òní olónìí.

9. Nítorí náà ni àwọn ẹ̀yà Lefi kò fi ní ìpín tabi ogún pẹlu àwọn arakunrin wọn. OLUWA ni ìpín wọn gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun yín ti wí fún wọn.)

10. “Mo wà ní orí òkè fún odidi ogoji ọjọ́ gẹ́gẹ́ bíi ti àkọ́kọ́, OLUWA sì tún gbọ́ ohùn mi, ó gbà láti má pa yín run.

11. OLUWA wí fún mi pé, ‘Gbéra, kí o máa lọ láti ṣáájú àwọn eniyan náà, kí wọ́n lè lọ gba ilẹ̀ tí mo búra fún wọn pé n óo fún wọn.’

12. “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin eniyan Israẹli, kò sí ohun tí OLUWA Ọlọrun yín fẹ́ kí ẹ ṣe, àfi pé kí ẹ bẹ̀rù rẹ̀, kí ẹ máa rìn ní ọ̀nà rẹ̀, kí ẹ fẹ́ràn rẹ̀ pẹlu gbogbo ọkàn yín ati ẹ̀mí yín,

13. kí ẹ sì pa àwọn òfin ati ìlànà rẹ̀, tí mo paláṣẹ fun yín lónìí mọ́, fún ire ara yín.

14. Wò ó, OLUWA Ọlọrun yín ni ó ni ọ̀run, ati ayé ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀;

15. sibẹsibẹ Ọlọrun fẹ́ràn àwọn baba yín tóbẹ́ẹ̀ tí ó yan ẹ̀yin arọmọdọmọ wọn, ó yàn yín láàrin gbogbo eniyan tí ó wà láyé.

Ka pipe ipin Diutaronomi 10