Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 1:8-19 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Ó ní, ‘Ẹ wò ó! Mo ti pèsè ilẹ̀ náà fun yín, ẹ lọ, kí ẹ sì gbà á; Èmi OLUWA ti búra láti fún Abrahamu ati Isaaki, ati Jakọbu, àwọn baba ńlá yín ati arọmọdọmọ wọn.’ ”

9. “Mo sọ fun yín nígbà náà pé, èmi nìkan kò ní lè máa ṣe àkóso yín.

10. OLUWA Ọlọrun yín ti sọ yín di pupọ, lónìí ẹ pọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run.

11. Kí OLUWA Ọlọrun àwọn baba ńlá yín jẹ́ kí ẹ tún pọ̀ jù báyìí lọ lọ́nà ẹgbẹrun. Kí ó sì bukun yín gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìlérí fun yín.

12. Báwo ni mo ṣe lè dá nìkan dàyàkọ ìnira yín ati ẹrù yín ati ìjà yín.

13. Mo ní kí ẹ yan àwọn ọlọ́gbọ́n, tí wọ́n ní ìmọ̀ ati ìrírí láàrin ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, n óo sì fi wọ́n ṣe olórí yín.

14. Ìdáhùn tí ẹ fún mi nígbà náà ni pé, ohun tí mo wí ni ó yẹ kí ẹ ṣe.

15. Mo bá fi mú àwọn olórí olórí ninu àwọn ẹ̀yà yín, àwọn tí wọ́n gbọ́n tí wọ́n sì ní ìrírí, mo yàn wọ́n gẹ́gẹ́ bí olórí fun yín. Mo fi àwọn kan jẹ balogun lórí ẹgbẹẹgbẹrun eniyan, àwọn mìíràn lórí ọgọọgọrun-un eniyan, àwọn mìíràn lórí araadọta eniyan; bẹ́ẹ̀ ni mo fi àwọn ẹlòmíràn jẹ balogun lórí eniyan mẹ́wàá mẹ́wàá, mo sì fi àwọn kan ṣe olórí ninu gbogbo ẹ̀yà yín.

16. “Mo pàṣẹ fún àwọn adájọ́ yín nígbà náà, mo ní, ‘Ẹ máa gbọ́ ẹjọ́ àwọn arakunrin yín, kí ẹ sì máa ṣe ìdájọ́ òdodo láàrin eniyan ati arakunrin rẹ̀, tabi àlejò tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀.

17. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe ojuṣaaju ninu ìdájọ́ yín; kì báà jẹ́ àwọn eniyan ńláńlá, kì báà jẹ́ àwọn mẹ̀kúnnù, bákan náà ni kí ẹ máa gbọ́ ẹjọ́ wọn. Ẹ kò gbọdọ̀ bẹ̀rù eniyan, nítorí Ọlọrun ni onídàájọ́. Bí ẹjọ́ kan bá le jù fun yín láti dá, ẹ kó o tọ̀ mí wá, n óo sì dá a.’

18. Gbogbo ohun tí ó yẹ kí ẹ ṣe nígbà náà ni mo pa láṣẹ fun yín.

19. “Gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun wa ti pàṣẹ fún wa nígbà náà, a gbéra ní Horebu, a sì la àwọn aṣálẹ̀ ńláńlá tí wọ́n bani lẹ́rù kọjá, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin náà ṣe rí i ní ojú ọ̀nà àwọn agbègbè olókè àwọn ará Amori; a sì dé Kadeṣi Banea.

Ka pipe ipin Diutaronomi 1