Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Daniẹli 7:4-13 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Ekinni dàbí kinniun, ó sì ní ìyẹ́ bíi ti idì. Mò ń wò ó títí tí ìyẹ́ rẹ̀ fi fà tu. A gbé e dìde lórí ẹsẹ̀ rẹ̀ mejeeji bí eniyan. Ó sì ń ronú bí eniyan.

5. “Ẹranko keji dàbí àmọ̀tẹ́kùn, ó gbé ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ kan sókè. Ó gbé egungun ìhà mẹta há ẹnu, ó wa eyín mọ́ ọn. Mo sì gbọ́ tí ẹnìkan sọ fún un pé, ‘Dìde, kí o sì máa jẹ ẹran sí i.’

6. “Bí mo ti ń wò mo tún rí ẹranko mìíràn tí ó dàbí ẹkùn, òun náà ní ìyẹ́ mẹrin lẹ́yìn. Ó ní orí mẹrin. A sì fún un ní agbára láti jọba.

7. “Lẹ́yìn èyí, ninu ìran tí mo rí ní òru náà, ẹranko kẹrin tí mo rí jáni láyà, ó bani lẹ́rù, ó sì lágbára pupọ. Ó tóbi, irin sì ni eyín rẹ̀. A máa fọ́ nǹkan túútúú, á jẹ ẹ́ ní àjẹrun, á sì fi ẹsẹ̀ tẹ àjẹkù rẹ̀ mọ́lẹ̀. Ó yàtọ̀ sí gbogbo àwọn ẹranko tí ó ti wà ṣáájú rẹ̀, ìwo mẹ́wàá ni ó ní.

8. Bí mo ti ń ronú nípa àwọn ìwo rẹ̀, ni mo rí i tí ìwo kékeré kan tún hù láàrin wọn, ìwo mẹta fà tu níwájú rẹ̀ ninu àwọn ìwo ti àkọ́kọ́. Ìwo kékeré yìí ní ojú bí eniyan, ó sì ní ẹnu tí ó fi ń sọ ọ̀rọ̀ ńláńlá.

9. “Bí mo ti ń wo ọ̀kánkán,mo rí àwọn ìtẹ́ kan tí a tẹ́.Ẹni Ayérayé sì jókòó lórí ìtẹ́ tirẹ̀,aṣọ rẹ̀ funfun bíi ẹ̀gbọ̀n òwú.Irun orí rẹ̀ náà dàbí irun aguntan funfun,ìtẹ́ rẹ̀ ń jó bí ahọ́n iná,kẹ̀kẹ́ abẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ sì dàbí iná.

10. Iná ń ṣàn jáde bí odò níwájú rẹ̀.Ẹgbẹẹgbẹrun ọ̀nà ẹgbẹẹgbẹrun ni àwọn tí ń ṣe iranṣẹ fún un,ọ̀kẹ́ àìmọye sì ni àwọn tí wọ́n dúró níwájú rẹ̀.Ìdájọ́ bẹ̀rẹ̀, a sì ṣí àwọn ìwé sílẹ̀.

11. “Mo wò yíká nítorí ọ̀rọ̀ ńláńlá tí ìwo kékeré yìí ń fi ẹnu sọ, mo sì rí i tí wọ́n pa ẹranko náà, tí wọ́n sì jó òkú rẹ̀ níná.

12. Ní ti àwọn ẹranko tí ó kù, a gba àṣẹ wọn, ṣugbọn a dá wọn sí fún àkókò kan, àní fún ìgbà díẹ̀.

13. “Ninu ìran, lóru, mo rí ẹnìkan tí ó rí bí Ọmọ Eniyan ninu awọsanma, ó lọ sí ọ̀dọ̀ Ẹni Ayérayé náà, ó sì fi ara rẹ̀ hàn níwájú rẹ̀.

Ka pipe ipin Daniẹli 7