Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Daniẹli 7:12-23 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Ní ti àwọn ẹranko tí ó kù, a gba àṣẹ wọn, ṣugbọn a dá wọn sí fún àkókò kan, àní fún ìgbà díẹ̀.

13. “Ninu ìran, lóru, mo rí ẹnìkan tí ó rí bí Ọmọ Eniyan ninu awọsanma, ó lọ sí ọ̀dọ̀ Ẹni Ayérayé náà, ó sì fi ara rẹ̀ hàn níwájú rẹ̀.

14. A sì fún Ẹni Ayérayé ní àṣẹ, ògo ati ìjọba, pé kí gbogbo eniyan ní gbogbo orílẹ̀-èdè ati ẹ̀yà máa sìn ín. Àṣẹ ayérayé tí kò lè yẹ̀ ni àṣẹ rẹ̀, ìjọba rẹ̀ kò sì lè parun.

15. “Ìran tí mo rí yìí bà mí lẹ́rù pupọ, ọkàn mi sì dààmú.

16. Mo bá súnmọ́ ọ̀kan ninu àwọn tí wọ́n dúró níbẹ̀, mo bèèrè ìtumọ̀ ohun tí mo rí, ó sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi, ó ní,

17. ‘Àwọn ọba ńlá mẹrin tí yóo jẹ láyé ni àwọn ẹranko ńláńlá mẹrin tí o rí.

18. Ṣugbọn àwọn eniyan mímọ́ Ẹni Gíga Jùlọ yóo gba ìjọba ayé, ìjọba náà yóo jẹ́ tiwọn títí lae, àní títí ayé àìlópin.’

19. “Mo tún fẹ́ mọ̀ nípa ẹranko kẹrin, tí ó yàtọ̀ sí gbogbo àwọn yòókù, tí ó bani lẹ́rù lọpọlọpọ, tí èékánná rẹ̀ jẹ́ idẹ, tí eyín rẹ̀ sì jẹ́ irin; tí ń jẹ àjẹrun, tí ó ń fọ́ nǹkan túútúú, tí ó sì ń fi ẹsẹ̀ tẹ àjẹkù rẹ̀ mọ́lẹ̀.

20. Mo fẹ́ mọ̀ nípa àwọn ìwo mẹ́wàá orí rẹ̀, ati ìwo kékeré, tí ó fa mẹta tí ó wà níwájú rẹ̀ tu, tí ó ní ojú, tí ń fi ẹnu rẹ̀ sọ ọ̀rọ̀ ńláńlá, tí ó sì dàbí ẹni pé ó ju gbogbo àwọn yòókù lọ.

21. “Bí mo ti ń wò ó, mo rí i ti ìwo yìí ń bá àwọn eniyan mímọ́ jà, tí ó sì ń ṣẹgun wọn,

22. títí tí Ẹni Ayérayé fi dé, tí ó dá àwọn ẹni mímọ́ ti Ẹni Gíga Jùlọ láre; tí ó sì tó àkókò fún àwọn ẹni mímọ́ láti gba ìjọba.

23. “Ó ṣe àlàyé rẹ̀ fún mi báyìí pé: ‘Ẹranko kẹrin ni ìjọba kẹrin tí yóo wà láyé, tí yóo sì yàtọ̀ sí gbogbo àwọn ìyókù. Yóo ṣẹgun gbogbo ayé, yóo tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀, yóo sì fọ́ ọ túútúú.

Ka pipe ipin Daniẹli 7