Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Daniẹli 4:1-12 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ọba Babiloni ranṣẹ sí gbogbo àwọn eniyan, ati gbogbo orílẹ̀-èdè ati ẹ̀yà ní gbogbo ayé, pé:“Kí alaafia wà pẹlu yín!

2. Ó tọ́ lójú mi láti fi àmì ati iṣẹ́ ìyanu, tí Ọlọrun tí ó ga jùlọ ṣe fún mi, hàn.

3. “Iṣẹ́ rẹ̀ tóbi gan-an!Iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ sì lágbára lọpọlọpọ!Títí ayérayé ni ìjọba rẹ̀,àtìrandíran rẹ̀ ni yóo sì máa jọba.

4. “Èmi, Nebukadinesari wà ninu ìdẹ̀ra ní ààfin mi, nǹkan sì ń dára fún mi.

5. Mo lá àlá kan tí ó bà mí lẹ́rù. Èrò ọkàn mi ati ìran tí mo rí lórí ibùsùn mi kó ìdààmú bá mi.

6. Nítorí náà, mo pàṣẹ pé kí wọ́n kó gbogbo àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n Babiloni wá sọ́dọ̀ mi, kí wọ́n wá túmọ̀ àlá náà fún mi.

7. Gbogbo àwọn pidánpidán, ati àwọn aláfọ̀ṣẹ, àwọn ará Kalidea, ati àwọn awòràwọ̀ bá péjọ siwaju mi; mo rọ́ àlá náà fún wọn, ṣugbọn wọn kò lè túmọ̀ rẹ̀ fún mi.

8. Lẹ́yìn gbogbo wọn patapata ni Daniẹli dé, tí a sọ ní Beteṣasari, orúkọ oriṣa mi, Daniẹli yìí ní ẹ̀mí Ọlọrun ninu. Mo rọ́ àlá mi fún un, mo ní:

9. Beteṣasari, olórí gbogbo àwọn pidánpidán, mo mọ̀ pé ẹ̀mí Ọlọrun mímọ́ wà ninu rẹ, ati pé o mọ gbogbo àṣírí. Gbọ́ àlá mi kí o sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi.

10. “Nígbà tí mo sùn, mo rí igi kan láàrin ayé, lójú ìran, igi náà ga lọpọlọpọ.

11. Igi náà bẹ̀rẹ̀ sí tóbi, ó sì lágbára; orí rẹ̀ kan ojú ọ̀run, kò sí ibi tí wọn kò ti lè rí i ní gbogbo ayé.

12. Ewé rẹ̀ lẹ́wà, ó so jìnwìnnì, oúnjẹ wà lórí rẹ̀ fún gbogbo eniyan, abẹ́ rẹ̀ ni àwọn ẹranko ń gbé, orí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ sì ni àwọn ẹyẹ ń sùn. Èso rẹ̀ ni gbogbo ẹ̀dá alààyè ń jẹ.

Ka pipe ipin Daniẹli 4