Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Daniẹli 2:29-36 BIBELI MIMỌ (BM)

29. “Kabiyesi! Bí o ti sùn, ò ń ronú ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀la, ẹni tí ń fi ohun ìjìnlẹ̀ han ni sì fi ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ hàn ọ́.

30. Ní tèmi, kì í ṣe pé mo gbọ́n ju àwọn yòókù lọ ni a ṣe fi ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ yìí hàn mí, bíkòṣe pé kí ọba lè mọ ìtumọ̀ rẹ̀, kí òye ohun tí ó ń rò sì lè yé e.

31. “Kabiyesi, o rí ère kan níwájú rẹ ní ojúran, ère yìí tóbi gan-an, ó mọ́lẹ̀, ó ń dán, ìrísí rẹ̀ sì bani lẹ́rù.

32. Wúrà ni orí rẹ̀, àyà ati apá rẹ̀ jẹ́ fadaka, ikùn rẹ̀ títí dé itan sì jẹ́ idẹ.

33. Irin ni òkè ẹsẹ̀ rẹ̀, ìsàlẹ̀ ẹsẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ irin tí a lú pọ̀ mọ́ amọ̀.

34. Bí o ti ń wò ó, òkúta kan là, ó sì ré bọ́ láti òkè, ó bá ère náà ní ẹsẹ̀ mejeeji tí ó jẹ́ àdàlú irin ati amọ̀, mejeeji sì fọ́ túútúú.

35. Lẹ́sẹ̀kan náà òkúta yìí bá fọ́ gbogbo ère náà, ati irin, ati amọ̀, ati idẹ, ati fadaka ati wúrà, ó rún gbogbo wọn wómúwómú, títí wọ́n fi dàbí ìyàngbò ní ibi ìpakà. Lẹ́yìn náà, afẹ́fẹ́ fẹ́ wọn lọ, a kò sì rí wọn mọ́ rárá. Òkúta tí ó kọlu ère náà di òkè ńlá, ó sì bo gbogbo ayé.

36. “Àlá náà nìyí; nisinsinyii, n óo sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún ọba.

Ka pipe ipin Daniẹli 2