Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Daniẹli 2:17-28 BIBELI MIMỌ (BM)

17. Daniẹli bá lọ sí ilé, ó sọ fún àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀: Hananaya, Miṣaeli, ati Asaraya,

18. pé kí wọ́n gbadura sí Ọlọrun ọ̀run fún àánú láti mọ àlá ọba ati ìtumọ̀ rẹ̀, kí wọ́n má baà pa òun ati àwọn ẹlẹgbẹ́ òun run pẹlu àwọn ọlọ́gbọ́n Babiloni.

19. Ọlọrun bá fi àṣírí náà han Daniẹli ní ojúran, lóru. Ó sì yin Ọlọrun ọ̀run lógo.

20. Ó ní, “Ẹni ìyìn ni Ọlọrun títí ayérayé,ẹni tí ó ní ọgbọ́n ati agbára.

21. Òun ní ń yí ìgbà ati àkókò pada;òun níí mú ọba kan kúrò lórí ìtẹ́,tíí sì í fi òmíràn jẹ.Òun níí fi ọgbọ́n fún ọlọ́gbọ́ntíí sì í fi ìmọ̀ fún àwọn ọ̀mọ̀ràn.

22. Òun níí fi àṣírí ati ohun ìjìnlẹ̀ hàn;ó mọ ohun tí ó wà ninu òkùnkùn,ìmọ́lẹ̀ sì ń bá a gbé.

23. Ìwọ Ọlọrun àwọn baba mi,ni mo fi ọpẹ́ ati ìyìn fún,nítorí o fún mi ní ọgbọ́n ati agbára,o sì ti fi ohun tí a bèèrè hàn mí,nítorí o ti fi ohun tí ọba ń bèèrè hàn wá.”

24. Daniẹli bá lọ sí ọ̀dọ̀ Arioku, ẹni tí ọba yàn pé kí ó pa àwọn ọlọ́gbọ́n Babiloni run, ó sọ fún un pé, “Má pa àwọn ọlọ́gbọ́n Babiloni run, mú mi lọ sí ọ̀dọ̀ ọba, n óo sì túmọ̀ àlá rẹ̀ fún un.”

25. Arioku bá mú Daniẹli lọ sí ọ̀dọ̀ ọba kíákíá. Ó sọ fún ọba pé: “Kabiyesi, mo ti rí ọkunrin kan ninu àwọn tí wọ́n kó lẹ́rú wá láti Juda, tí ó le túmọ̀ àlá náà fún ọba.”

26. Ọba bi Daniẹli, tí wọ́n sọ ní Beteṣasari ní èdè Babiloni pé, “Ǹjẹ́ o lè rọ́ àlá mi fún mi, kí o sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀?”

27. Daniẹli dá ọba lóhùn pé, “Kò sí ọlọ́gbọ́n kan, tabi aláfọ̀ṣẹ, tabi pidánpidán, tabi awòràwọ̀ tí ó lè sọ àṣírí ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ tí ọba ń bèèrè yìí fún un.

28. Ṣugbọn Ọlọrun kan ń bẹ ní ọ̀run, tí ń fi àṣírí nǹkan ìjìnlẹ̀ hàn. Òun ni ó fi ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀la han Nebukadinesari ọba. Àlá tí o lá, ati ìran tí o rí ní orí ibùsùn rẹ nìyí:

Ka pipe ipin Daniẹli 2