Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Daniẹli 12:8-13 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Mo gbọ́ tí ó ń sọ̀rọ̀, ṣugbọn ohun tí ń sọ kò yé mi. Mo bá bèèrè pé, “Olúwa mi, níbo ni nǹkan wọnyi yóo yọrí sí?”

9. Ó dáhùn pé, “Ìwọ Daniẹli, máa bá tìrẹ lọ, nítorí a ti pa ọ̀rọ̀ yìí mọ́, a sì ti fi èdìdì dì í, títí di àkókò ìkẹyìn.

10. Ọ̀pọ̀ eniyan ni yóo wẹ ara wọn mọ́, tí wọn yóo sọ ara wọn di funfun, wọn yóo sì mọ́; ṣugbọn àwọn ẹni ibi yóo máa ṣe ibi; kò ní sí ẹni ibi tí òye yóo yé; ṣugbọn yóo yé àwọn ọlọ́gbọ́n.

11. “Láti ìgbà tí wọn yóo mú ẹbọ ojoojumọ kúrò, tí wọn yóo gbé ohun ìríra sí ibi mímọ́, yóo jẹ́ eedegbeje ọjọ́ ó dín ọjọ́ mẹ́wàá (1,290).

12. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá forítì í ní gbogbo eedegbeje ọjọ́ ó lé ọjọ́ marundinlogoji (1,335) náà.

13. “Ṣugbọn, ìwọ Daniẹli, máa ṣe tìrẹ lọ títí dé òpin. O óo lọ sí ibi ìsinmi, ṣugbọn lọ́jọ́ ìkẹyìn, o óo dìde nílẹ̀ o óo sì gba ìpín tìrẹ tí a ti fi sílẹ̀ fún ọ.”

Ka pipe ipin Daniẹli 12