Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Daniẹli 12:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Angẹli tí ó wọ aṣọ funfun náà ní, “Ní àkókò náà Mikaeli, aláṣẹ ńlá, tí ń dáàbò bo àwọn eniyan rẹ, yóo dìde. Àkókò ìyọnu yóo dé, irú èyí tí kò tíì sí rí láti ọjọ́ tí aláyé ti dáyé; ṣugbọn a óo gba gbogbo àwọn eniyan rẹ, tí a bá kọ orúkọ wọn sinu ìwé náà là.

2. Ọ̀pọ̀ ninu àwọn tí ó ti kú, tí wọ́n ti sin ni yóo jí dìde, àwọn kan óo jí sí ìyè ainipẹkun, àwọn mìíràn óo sì jí sí ìtìjú ati ẹ̀sín ainipẹkun.

3. Àwọn ọlọ́gbọ́n yóo máa tàn bí ìmọ́lẹ̀ ojú ọ̀run, àwọn tí wọn ń yí eniyan pada sí ọ̀nà òdodo yóo máa tàn bí ìràwọ̀ lae ati títí lae.”

4. Ó ní, “Ṣugbọn ìwọ Daniẹli, pa ìwé náà dé, kí o sì fi èdìdì dì í títí di àkókò ìkẹyìn. Nítorí àwọn eniyan yóo máa sá síhìn-ín, sá sọ́hùn-ún, ìmọ̀ yóo sì pọ̀ sí i.”

5. Nígbà náà ni mo rí i tí àwọn meji dúró létí bèbè odò kan, ọ̀kan lápá ìhín, ọ̀kan lápá ọ̀hún.

6. Ọ̀kan ninu wọn bi ẹni tí ó wọ aṣọ funfun, tí ó wà lókè odò pé, “Nígbà wo ni àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ń bani lẹ́rù wọnyi yóo dópin?”

7. Ọkunrin tí ó wọ aṣọ funfun, tí ó wà lókè odò na ọwọ́ rẹ̀ mejeeji sókè ọ̀run, mo sì gbọ́ tí ó fi orúkọ ẹni tí ó wà láàyè títí lae búra pé, “Ọdún mẹta ààbọ̀ ni yóo jẹ́. Nígbà tí wọn bá gba agbára lọ́wọ́ àwọn eniyan Ọlọrun patapata, ni gbogbo nǹkan wọnyi yóo ṣẹlẹ̀.”

8. Mo gbọ́ tí ó ń sọ̀rọ̀, ṣugbọn ohun tí ń sọ kò yé mi. Mo bá bèèrè pé, “Olúwa mi, níbo ni nǹkan wọnyi yóo yọrí sí?”

Ka pipe ipin Daniẹli 12