Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 9:24-28 BIBELI MIMỌ (BM)

24. Nígbà tí ó yá, ọmọ ọba Farao, iyawo Solomoni kó kúrò ní ìlú Dafidi, ó lọ sí ilé tí Solomoni kọ́ fún un. Lẹ́yìn náà ni Solomoni kọ́ ìlú Milo.

25. Ẹẹmẹta lọ́dún ni Solomoni máa ń rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia lórí pẹpẹ tí ó kọ́ fún OLUWA, a sì máa sun turari níwájú OLUWA. Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe parí kíkọ́ ilé náà.

26. Solomoni kan ọpọlọpọ ọkọ̀ ojú omi ní Esiongeberi lẹ́bàá Eloti, ní etí Òkun Pupa ní ilẹ̀ Edomu.

27. Hiramu ọba fi àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n mọ̀ nípa ọkọ̀ ojú omi, lé àwọn ọkọ̀ náà, ó kó wọn rán àwọn iranṣẹ Solomoni sí i.

28. Wọ́n tu ọkọ̀ lọ sí ilẹ̀ Ofiri, wọ́n sì kó wúrà tí ó tó okoolenirinwo (420) ìwọ̀n talẹnti bọ̀ wá fún Solomoni ọba.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 9