Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 8:6-11 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Lẹ́yìn náà, àwọn alufaa gbé Àpótí Ẹ̀rí OLUWA wá sí ààyè rẹ̀ ninu ibi mímọ́ ti inú, ní Ibi-Mímọ́-Jùlọ, lábẹ́ ìyẹ́ àwọn kerubu.

7. Nítorí àwọn kerubu yìí na ìyẹ́ wọn bo ibi tí wọ́n gbé Àpótí Ẹ̀rí náà sí, wọ́n sì dàbí ìbòrí fún Àpótí Ẹ̀rí ati àwọn ọ̀pá rẹ̀.

8. Àwọn ọ̀pá tí wọ́n fi ń gbé Àpótí Ẹ̀rí náà gùn tóbẹ́ẹ̀ tí ẹni tí ó bá dúró ninu Ibi-Mímọ́ fi lè rí orí wọn níwájú Ibi-Mímọ́ ti inú. Ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò lè rí wọn láti ìta. Àwọn ọ̀pá náà wà níbẹ̀ títí di òní yìí.

9. Kò sí ohunkohun ninu Àpótí Ẹ̀rí náà, àfi tabili òkúta meji tí Mose kó sinu rẹ̀ ní òkè Sinai, níbi tí OLUWA ti bá àwọn ọmọ Israẹli dá majẹmu, nígbà tí wọn ń ti Ijipti bọ̀.

10. Bí àwọn alufaa ti jáde láti inú Ibi-Mímọ́ náà, ìkùukùu kún inú rẹ̀,

11. tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn alufaa kò lè dúró láti ṣe iṣẹ́ ìsìn, nítorí ògo OLUWA kún inú ilé OLUWA.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 8