Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 8:19-36 BIBELI MIMỌ (BM)

19. ṣugbọn kì í ṣe òun ni yóo kọ́ ilé ìsìn náà, ọmọ bíbí rẹ̀ ni yóo kọ́ ọ.

20. “Nisinsinyii OLUWA ti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ: mo ti gorí oyè lẹ́yìn Dafidi, baba mi, mo ti jọba ní ilẹ̀ Israẹli bí OLUWA ti ṣèlérí; mo sì ti kọ́ ilé fún OLUWA Ọlọrun Israẹli.

21. Mo ti ṣètò ibìkan ninu ilé náà fún Àpótí Ẹ̀rí OLUWA, tí tabili òkúta tí wọ́n kọ majẹmu sí wà ninu rẹ̀, majẹmu tí OLUWA bá àwọn baba ńlá wa dá nígbà tí ó ń kó wọn jáde láti ilẹ̀ Ijipti.”

22. Solomoni dúró níwájú pẹpẹ níwájú àwùjọ àwọn ọmọ Israẹli, ó gbé ọwọ́ rẹ̀ mejeeji sókè.

23. Ó bẹ̀rẹ̀ sí gbadura, ó ní, “OLUWA Ọlọrun Israẹli, kò sí Ọlọrun kan tí ó dàbí rẹ̀ lókè ọ̀run tabi ní ayé yìí, tíí máa pa majẹmu rẹ̀ mọ́, tíí sì máa fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn sí àwọn iranṣẹ rẹ̀, tí ń fi tọkàntọkàn gbọ́ràn sí i lẹ́nu.

24. O ti mú ìlérí tí o ṣe fún iranṣẹ rẹ, Dafidi, baba mi, ṣẹ. O ṣe ìlérí fún un nítòótọ́, o sì mú un ṣẹ lónìí.

25. Ǹjẹ́ nisinsinyii, OLUWA Ọlọrun Israẹli, mo bẹ̀ ọ́, mú àwọn ìlérí tí o ṣe fún iranṣẹ rẹ, Dafidi, baba mi ṣẹ, pé, arọmọdọmọ rẹ̀ ni yóo máa jọba ní Israẹli títí lae, bí wọ́n bá ṣọ́ra ní ọ̀nà wọn, tí wọ́n sì bá mi rìn bí ìwọ ti bá mi rìn.

26. Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun Israẹli, mú ìlérí tí o ṣe fún iranṣẹ rẹ, Dafidi, baba mi ṣẹ.

27. “Ṣugbọn, ǹjẹ́ ìwọ Ọlọrun lè gbé inú ayé yìí? Nítorí pé bí gbogbo ọ̀run ti tóbi tó, kò gbà ọ́; kí á má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti ilé ìsìn tí mo kọ́ fún ọ?

28. OLUWA Ọlọrun mi, fi etí sí adura èmi iranṣẹ rẹ, kí o sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ tí mò ń bẹ̀ níwájú rẹ lónìí.

29. Kí ojú rẹ lè máa wà lára ilé ìsìn yìí tọ̀sán-tòru, níbi tí o sọ pé o óo yà sọ́tọ̀ fún orúkọ rẹ. Kí o lè gbọ́ adura tí iranṣẹ rẹ ń gbà sí ibí yìí.

30. Máa gbọ́ ẹ̀bẹ̀ iranṣẹ rẹ ati adura àwọn ọmọ Israẹli, eniyan rẹ, nígbà tí wọ́n bá kọjú sí ilé yìí, tí wọ́n sì gbadura, máa gbọ́ tiwa láti ibùgbé rẹ lọ́run, kí o sì máa dáríjì wá.

31. “Bí ẹnìkan bá ṣẹ ọmọnikeji rẹ̀ tí wọ́n sì ní kí ó wá búra, tí ó bá wá tí ó sì búra níwájú pẹpẹ rẹ ninu ilé ìsìn yìí,

32. OLUWA, gbọ́ lọ́run lọ́hùn-ún, kí o sì ṣe ìdájọ́ àwọn iranṣẹ rẹ. Jẹ ẹni tí ó bá jẹ̀bi ní ìyà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀; dá ẹni tí ó bá jàre láre, kí o sì san ẹ̀san òdodo rẹ̀ fún un.

33. “Nígbà tí àwọn ọ̀tá bá ṣẹgun àwọn ọmọ Israẹli, eniyan rẹ, nítorí pé wọ́n dẹ́ṣẹ̀ sí ọ́, lẹ́yìn náà, tí wọ́n bá tún yipada sí ọ, tí wọ́n jẹ́wọ́ orúkọ rẹ ninu ilé yìí, tí wọ́n gbadura sí ọ, tí wọ́n bẹ̀bẹ̀,

34. gbọ́ adura wọn lọ́run lọ́hùn-ún, dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n, kí o sì mú wọn pada wá sórí ilẹ̀ tí o fún àwọn baba ńlá wọn.

35. “Nígbà tí o kò bá jẹ́ kí òjò rọ̀, nítorí pé wọ́n ṣẹ̀ ọ́, tí wọ́n bá ronupiwada tí wọ́n sì kọjú sí ilé ìsìn yìí, tí wọ́n gbadura sí ọ, nígbà tí o bá jẹ wọ́n níyà,

36. gbọ́ adura wọn lọ́run lọ́hùn-ún, dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji Israẹli, iranṣẹ rẹ, àní, àwọn eniyan rẹ, kí o sì kọ́ wọn ní ọ̀nà rere tí wọn yóo máa tọ̀; lẹ́yìn náà, rọ òjò sórí ilẹ̀ rẹ tí o fi fún àwọn eniyan rẹ bí ohun ìní.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 8