Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 8:14-25 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Solomoni ọba yipada, ó kọjú sí àwọn eniyan níbi tí wọ́n dúró sí, ó sì súre fún wọn.

15. Ó ní, “Ìyìn ni fún OLUWA Ọlọrun Israẹli, tí ó mú ìlérí tí ó ṣe fún Dafidi, baba mi, ṣẹ, tí ó ní,

16. ‘Láti ìgbà tí mo ti kó àwọn eniyan mi jáde láti ilẹ̀ Ijipti, n kò yan ìlú kan ninu gbogbo ilẹ̀ Israẹli pé kí àwọn ọmọ Israẹli kọ́ ilé ìsìn sibẹ, níbi tí wọn óo ti máa sìn mí, ṣugbọn, mo yan Dafidi láti jọba lórí Israẹli, eniyan mi.’ ”

17. Solomoni tún fi kún un pé, “Ó jẹ́ èrò ọkàn baba mi láti kọ́ ilé fún OLUWA Ọlọrun Israẹli.

18. Ṣugbọn OLUWA sọ fún un pé nítòótọ́, ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ ni láti kọ́ ilé fún mi, ó sì dára bẹ́ẹ̀,

19. ṣugbọn kì í ṣe òun ni yóo kọ́ ilé ìsìn náà, ọmọ bíbí rẹ̀ ni yóo kọ́ ọ.

20. “Nisinsinyii OLUWA ti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ: mo ti gorí oyè lẹ́yìn Dafidi, baba mi, mo ti jọba ní ilẹ̀ Israẹli bí OLUWA ti ṣèlérí; mo sì ti kọ́ ilé fún OLUWA Ọlọrun Israẹli.

21. Mo ti ṣètò ibìkan ninu ilé náà fún Àpótí Ẹ̀rí OLUWA, tí tabili òkúta tí wọ́n kọ majẹmu sí wà ninu rẹ̀, majẹmu tí OLUWA bá àwọn baba ńlá wa dá nígbà tí ó ń kó wọn jáde láti ilẹ̀ Ijipti.”

22. Solomoni dúró níwájú pẹpẹ níwájú àwùjọ àwọn ọmọ Israẹli, ó gbé ọwọ́ rẹ̀ mejeeji sókè.

23. Ó bẹ̀rẹ̀ sí gbadura, ó ní, “OLUWA Ọlọrun Israẹli, kò sí Ọlọrun kan tí ó dàbí rẹ̀ lókè ọ̀run tabi ní ayé yìí, tíí máa pa majẹmu rẹ̀ mọ́, tíí sì máa fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn sí àwọn iranṣẹ rẹ̀, tí ń fi tọkàntọkàn gbọ́ràn sí i lẹ́nu.

24. O ti mú ìlérí tí o ṣe fún iranṣẹ rẹ, Dafidi, baba mi, ṣẹ. O ṣe ìlérí fún un nítòótọ́, o sì mú un ṣẹ lónìí.

25. Ǹjẹ́ nisinsinyii, OLUWA Ọlọrun Israẹli, mo bẹ̀ ọ́, mú àwọn ìlérí tí o ṣe fún iranṣẹ rẹ, Dafidi, baba mi ṣẹ, pé, arọmọdọmọ rẹ̀ ni yóo máa jọba ní Israẹli títí lae, bí wọ́n bá ṣọ́ra ní ọ̀nà wọn, tí wọ́n sì bá mi rìn bí ìwọ ti bá mi rìn.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 8