Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 7:7-16 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Ó kọ́ gbọ̀ngàn ìtẹ́ kan, níbi tí yóo ti máa dájọ́; igi kedari ni wọ́n fi ṣe ara ògiri rẹ̀ láti òkè délẹ̀.

8. Ó kọ́ ilé tí òun alára óo máa gbé sí àgbàlá tí ó wà lẹ́yìn gbọ̀ngàn bí ó ti kọ́ àwọn ilé yòókù; ó sì kọ́ irú gbọ̀ngàn yìí gan-an fún ọmọ ọba Farao tí ó gbé ní iyawo.

9. Òkúta olówó ńlá, tí wọ́n fi ayùn gé tinú-tẹ̀yìn, ni wọ́n fi kọ́ gbogbo ilé ati àgbàlá rẹ̀, láti ìpìlẹ̀ títí dé òrùlé rẹ̀, ati láti àgbàlá ilé OLUWA títí dé àgbàlá ńlá náà.

10. Òkúta ńláńlá, olówó ńláńlá, onígbọ̀nwọ́ mẹjọ ati onígbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ni wọ́n fi ṣe ìpìlẹ̀ ilé náà.

11. Òkúta olówó ńlá tí a wọ̀n kí á tó gé e, ati igi kedari, ni wọ́n fi ṣe ògiri rẹ̀.

12. Ìlè mẹta mẹta òkúta gbígbẹ́ tí a fi ìlé kan igi kedari là láàrin, ni wọ́n fi kọ́ àgbàlá ńlá náà yípo. Bẹ́ẹ̀ náà sì ni àgbàlá ti inú ilé OLUWA ati yàrá àbáwọlé.

13. Solomoni ọba ranṣẹ pé kí wọ́n lọ mú Huramu wá láti Tire,

14. ará Tire ni baba rẹ̀, ṣugbọn opó ọmọ ẹ̀yà Nafutali kan ni ìyá rẹ̀. Baba rẹ̀ ti jáde láyé, ṣugbọn nígbà ayé rẹ̀, òun náà mọ iṣẹ́ àgbẹ̀dẹ bàbà dáradára. Huramu gbọ́n, ó lóye, ó sì mọ bí a tíí fi idẹ ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ọnà. Ó tọ Solomoni lọ, ó sì bá a ṣe gbogbo iṣẹ́ rẹ̀.

15. Ó fi bàbà ṣe òpó meji; gíga ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ igbọnwọ mejidinlogun, àyíká rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mejila, ó ní ihò ninu, nínípọn rẹ̀ sì jẹ́ ìka mẹrin. Bákan náà ni òpó keji.

16. Ó sì rọ ọpọ́n bàbà meji, ó gbé wọn ka orí àwọn òpó náà. Gíga àwọn ọpọ́n náà jẹ́ igbọnwọ marun-un marun-un.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 7